Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2021

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2021
  • Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 87

  • Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 239

  • Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 119,297

  • Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 21,367,603

  • Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 20,746

  • Góńgó Akéde *: 8,686,980

  • Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,480,147

  • Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2020: 0.7

  • Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi *: 171,393

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé * Lóṣooṣù: 1,350,138

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 398,504

  • Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 1,423,039,931

  • Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * Lóṣooṣù: 5,908,167

Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2021, * àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (229) mílíọ̀nù dọ́là láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó dín márùn-ún (20,595). Gbogbo wọn jẹ́ ara Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ Akéde ni ẹni tó ń kéde tàbí tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Tó o bá fẹ́ àlàyé nípa bá a ṣe mọ iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun tẹ́nì kan máa ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ Aṣáájú-ọ̀nà ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ti ṣe ìrìbọmi tó sì níwà tó dáa. Ó pinnu láti máa lo iye wákàtí kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lóṣooṣù.

^ Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2021 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2020, sí August 31, 2021.