Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2020

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2020
  • Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 87

  • Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240

  • Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 120,387

  • Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 17,844,773

  • Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 21,182

  • Góńgó Akéde *: 8,695,808

  • Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,424,185

  • Iye Tá A Fi Dín sí Ti Ọdún 2019: 46,823

  • Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi *: 241,994

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé * Lóṣooṣù: 1,299,619

  • Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 338,568

  • Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 1,669,901,531

  • Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì * Lóṣooṣù: 7,705,765

Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2020, * àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kànlélọ́gbọ̀n (231) mílíọ̀nù dọ́là láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún (20,994). Gbogbo wọn wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 7 Akéde ni àwọn tó ń kéde tàbí tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa bá a ṣe mọ iye wọn, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ohun tẹ́nì kan máa ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 11 Aṣáájú-ọ̀nà ni Ẹlẹ́rìí kan tó ti ṣe ìrìbọmi tó sì níwà tó dáa. Ó pinnu láti máa lo iye wákàtí kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lóṣooṣù.

^ ìpínrọ̀ 14 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Là Ń Pè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” lórí ìkànnì jw.org/yo.

^ ìpínrọ̀ 15 Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2020 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2019, ó sì parí ní August 31, 2020.