APÁ 1
Ìgbà Ìṣẹ̀dá sí Ìgbà Ìkún-Omi
Ibo ni ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ti wá? Báwo ni oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe di ohun tó wà? Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó tọ̀nà nígbà tó sọ pé Ọlọ́run ló dá wọn. Nítorí náà, àwọn ìtàn Bíbélì nípa ìṣẹ̀dá la fi bẹ̀rẹ̀ ìwé wa yìí.
Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, tí wọ́n jọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá. Áńgẹ́lì ni wọ́n. Àmọ́, àwọn èèyàn bíi tiwa ni Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé fún. Nítorí náà, Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń jẹ́ Ádámù àti Éfà ó sì fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan. Àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wọ́n sì pàdánù ẹ̀tọ́ wọn láti máa wà láàyè nìṣó.
Tá a bá ro gbogbo rẹ̀ pọ̀, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá Ádámù títí di ìgbà Ìkún-omi ńlá, ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [1,656] ọdún. Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ẹni burúkú ló wà. Ní ọ̀run, Sátánì àti àwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí a kò lè fojú rí wà. Lórí ilẹ̀ ayé, Kéènì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn búburú mìíràn wà títí kan àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n lágbára lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́ àwọn èèyàn rere tún wà lórí ilẹ̀ ayé. Lára wọn ni Ébẹ́lì, Énọ́kù àti Nóà. A ó kà nípa gbogbo àwọn wọ̀nyí àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ní Apá KÌÍNÍ.
NÍ APÁ YÌÍ
ÌTÀN 1
Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí í Ṣẹ̀dá Àwọn Nǹkan
Ìtàn ìṣẹ̀dá tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì dùn, ó sì rọrùn lóye, àní fún àwọn ọmọdé pàápàá.
ÌTÀN 2
Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan
Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣe sọ, Ọlọ́run dá ọgbà Édẹ́nì lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ayé rẹwà bí ọgbà Édẹ́nì.
ÌTÀN 3
Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì. Àwọn ló kọ́kọ́ ṣègbeyàwó láyé.
ÌTÀN 5
Ìgbésí Ayé Líle Koko Bẹ̀rẹ̀
Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà kúrò ní ọgbà Édẹ́nì, wọ́n kojú oríṣiríṣi ìṣòro. Tó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ ti Ọlọ́run ni, ìgbé ayé àwọn àti àwọn ọmọ wọn ì bá ládùn, ì bá sì lóyin.
ÌTÀN 6
Ọmọ Rere àti Ọmọ Búburú
Ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ irú ẹni tó yẹ ká jẹ́ àti àwọn ìwà tó yẹ ká yì pa dà kó tó pẹ́ jù
ÌTÀN 7
Ọkùnrin Onígboyà
Bí Énọ́kù ṣe nígboyà jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè máa ṣe ohun rere tí àwọn tó yí i ká bá tiẹ̀ ń ṣe ohun búburú.
ÌTÀN 8
Àwọn Òmìrán ní Ayé
Jẹ́nẹ́sísì orí 6 sọ nípa àwọn òmìrán tó ń ṣe àwọn èèyàn léṣe. Néfílímù ni wọ́n ń pé àwọn òmìrán yìí, àwọn ni ọmọ tí àwọn áńgẹ́lì tó fi ọ̀run sílẹ̀ wá sáyé bí.
ÌTÀN 9
Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
Nóà àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún Omi já nítorí pé wọ́n gbọ́ràn sí Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn yóòkù ò gbọ́ràn.
ÌTÀN 10
Ìkún-Omi Ńlá
Àwọn èèyàn fi Nóà ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó kìlọ̀ fún wọn nípa Ìkún-Omi. Àmọ́, wọn ò rẹ́rìn-ín mọ nígbà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Kọ́ nípa bí ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn ṣe gba Nóà àti ìdílé rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko là.