Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 10

Ìkún-Omi Ńlá

Ìkún-Omi Ńlá

ÀWỌN èèyàn tí kò sí nínú ọkọ̀ ń bá ìgbésí ayé wọn nìṣó bíi ti tẹ́lẹ̀. Wọn ò tíì gbà síbẹ̀síbẹ̀ pé Ìkún-omi máa dé. Ẹ̀rín yẹ̀yẹ́ tí wọn ń rín tiẹ̀ ti ní láti légbá kan sí i. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí ẹnu wọ́n fi wọhò, tí wọ́n dákẹ́ ẹ̀rín yẹ̀yẹ́ tí wọn ń rín.

Òjijì ni òjò dédé bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Ó ń rọ̀ láti ọ̀run wá bí ìgbà tí omi ń dà láti inú korobá. Àṣé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Nóà! Ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù nísinsìnyí fún ẹnikẹ́ni láti wọ inú ọkọ̀ áàkì náà. Jèhófà ti sé ilẹ̀kùn ẹ̀ pinpin.

Kò pẹ́, kò jìnnà, omi ti bo gbogbo ilẹ̀. Omi náà wá dà bí odò ńlá. Omi náà ń bì lu àwọn igi àti òkúta ńlá, ó sì ń hó yèè. Ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn èèyàn tó wà lóde áàkì. Wọ́n gun orí àwọn òkè ńlá lọ. Áà, ó mà ṣe o, wọn ì bá mọ̀ kí wọ́n ti fetí sí Nóà kí wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ nígbà tí wọ́n ṣì lè ráyè wọlé! Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹpa ò bóró mọ́, ó ti pẹ́ jù.

Omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i gan-an. Ogójì ọ̀sán àti ogójì òru ni omi náà fi ń ya wálẹ̀ látojú sánmà. Ó kún bo gbogbo ẹ̀gbẹ́ àwọn òkè ńlá, láìpẹ́ omi bo gbogbo àwọn òkè tó ga jù lọ pàápàá mọ́lẹ̀. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí gan-an, gbogbo àwọn èèyàn àti ẹranko tí kò sí nínú ọkọ̀ náà ló kú. Ṣùgbọ́n kò sí nǹkan tó ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀.

Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ kan ọkọ̀ náà dáadáa. Omi gbé e sókè, ó sì léfòó téńté sójú omi. Nígbà tó yá, ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí òjò náà dáwọ́ dúró, oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí í ràn. Ó ga jù! Ibi gbogbo dà bí òkun ńlá kan. Ohun kan ṣoṣo tí èèyàn lè rí ni ọkọ̀ áàkì tó léfòó téńté lójú omi.

Àwọn òmìrán ò sí mọ́ báyìí o. Wọn ò tún ní máa pa àwọn èèyàn lára mọ́. Gbogbo wọn ló ti kú, pẹ̀lú ìyá wọn àti gbogbo àwọn èèyàn búburú yòókù. Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn bàbá wọn?

Rántí pé àwọn bàbá wọn kì í ṣe èèyàn gidi bíi tiwa. Áńgẹ́lì tó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run láti wá máa gbé láyé bí èèyàn ni wọ́n. Nítorí náà, nígbà tí Ìkún-omi dé, wọn ò kú pẹ̀lú àwọn èèyàn tó kù. Wọ́n bọ́ àwọ̀ èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀ sílẹ̀, wọ́n sì padà lọ sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ò tún gbà wọ́n láyè mọ́ láti wà lára àwọn áńgẹ́lì Rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n di áńgẹ́lì Sátánì. Ẹ̀mí èṣù sì ni orúkọ tí Bíbélì pè wọ́n.

Wàyí o, Ọlọ́run mú kí afẹ́fẹ́ fẹ́, omi tó kún náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, ọkọ̀ Nóà gúnlẹ̀ sórí ṣóńṣó òkè gíga kan. Ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà bojú wo òde, wọ́n rí orí àwọn òkè ńlá. Omi náà ń túbọ̀ lọ sílẹ̀ sáá.

Ni Nóà bá jẹ́ kí ẹyẹ dúdú kan tá à ń pè ní ẹyẹ ìwò jáde nínú ọkọ̀. Tí ẹyẹ yìí bá ti fò jáde, á tún fò padà, nítorí pé kò rí ibi tó dára láti bà sí. Bó ṣe ń ṣe nìyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, tó bá sì ti fò padà, á bà sórí ọkọ̀ náà.

Nóà ṣáà fẹ́ mọ̀ bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, nítorí náà, ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde látinú ọkọ̀ áàkì. Ṣùgbọ́n ẹyẹ àdàbà yìí pẹ̀lú tún padà nítorí kò rí ibi tí yóò bà sí. Nóà tún rán an jáde lẹ́ẹ̀kejì, lọ́tẹ̀ yìí ó fi ẹnu rẹ̀ já ewé ólífì kan bọ̀. Nípa báyìí, Nóà mọ̀ pé omi náà ti lọ sílẹ̀ dáadáa. Nóà bá tún rán àdàbà náà jáde nígbà kẹta, lọ́tẹ̀ yìí, àmọ́ lọ́tẹ yìí kò padà, ó ti rí ibi gbígbẹ kan tó lè máa gbé.

Ọlọ́run wá bá Nóà sọ̀rọ̀. Ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé: ‘Jáde kúrò nínú ọkọ̀. Mú gbogbo ìdílé rẹ àtàwọn ẹranko jáde pẹ̀lú rẹ.’ Ó ti ju odindi ọdún kan lọ tí wọ́n ti wà nínú ọkọ̀ áàkì. Nítorí náà, ó dájú pé inú wọn á dùn gan-an láti tún padà fi ẹsẹ wọn tẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i tí wọ́n sì wà láàyè!