ÌTÀN 4
Ìdí Tí Wọ́n Fi Pàdánù Ibùgbé Wọn
WO OHUN tó ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí. Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà ẹlẹ́wà tó wà ní Édẹ́nì. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á?
Ohun tó fà á ni pé, wọ́n ṣe ohun kan tó burú gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi lé wọn jáde. Ǹjẹ́ o mọ ohun búburú tí Ádámù àti Éfà ṣe?
Wọ́n ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe. Ọlọ́run sọ fún wọn pé èyí tó bá wù wọ́n ni wọ́n lè jẹ nínú èso àwọn igi tó wà nínú ọgbà náà. Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ lára èso igi kan báyìí, pé tí wọ́n bá jẹ ẹ́, ńṣe ni wọ́n máa kú. Ó sọ pé ti tòun ni igi náà. Àwa náà kúkú mọ̀ pé kò dára láti mú ohun tó jẹ́ ti ẹlòmíràn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí lohun tó wá ṣẹlẹ̀?
Lọ́jọ́ kan tí Éfà dá wà nínú ọgbà, ejò kan bá a sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ èyí kò yà ẹ́ lẹ́nu? Ejò yẹn sọ fún Éfà pé kó jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nígbà tí Jèhófà dá ejò, kò dá a pé kó máa sọ̀rọ̀ bíi ti èèyàn. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé ẹlòmíì ló mú kí ejò yẹn sọ̀rọ̀. Ta lẹni náà?
Kì í ṣe Ádámù. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni tí Jèhófà dá kó tó dá ilẹ̀ ayé. Áńgẹ́lì ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyẹn, a ò sì lè rí wọn. Áńgẹ́lì tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí ti di agbéraga. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ó yẹ kóun pẹ̀lú jẹ́ aláṣẹ bíi ti Ọlọ́run. Ó sì fẹ́ káwọn èèyàn máa gbọ́ràn sóun lẹ́nu dípò kí wọ́n máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Áńgẹ́lì yìí ló mú kí ejò yẹn sọ̀rọ̀.
Áńgẹ́lì yìí rí Éfà tàn jẹ. Nígbà tó sọ fún Éfà pé ó máa dà bí Ọlọ́run bó bá jẹ èso náà, Éfà gbà á gbọ́. Ó jẹ ẹ́, Ádámù náà sì jẹ ẹ́. Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ìdí rèé tí wọ́n fi pàdánù ọgbà dáradára tó jẹ́ ibùgbé wọn.
Ṣùgbọ́n, lọ́jọ́ kan Ọlọ́run á rí sí i pé gbogbo ilẹ̀ ayé di ibi ẹlẹ́wà bí ọgbà Édẹ́nì. Tó bá yá, a óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè dá sí mímú kí ilẹ̀ ayé di ọgbà ẹlẹ́wà. Ṣùgbọ́n, ní báyìí ná, jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà.