Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 2

Láti Ìgbà Ìkún-Omi Títí Dé Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì

Láti Ìgbà Ìkún-Omi Títí Dé Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì

Ẹni mẹ́jọ péré ló la Ìkún-omi já, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i títí iye wọn fi tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé àádọ́ta àti méjì [352] ọdún lẹ́yìn Ìkún-omi ni wọ́n bí Ábúráhámù. A óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe pa ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù mọ́ nípa fífún un ní ọmọ kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì. Ísákì pẹ̀lú bí ọmọ méjì. Nínú ọmọ méjì tí Ísákì bí yìí, èyí tó ń jẹ́ Jékọ́bù ni Ọlọ́run yàn.

Jékọ́bù ní ìdílé ńlá, ó bí ọmọkùnrin méjìlá àti àwọn ọmọbìnrin mélòó kan. Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù mẹ́wàá kórìíra Jósẹ́fù àbúrò wọn, wọ́n sì tà á lẹ́rú sí Íjíbítì. Nígbẹ̀yìn, Jósẹ́fù di alákòóso ńlá ní Íjíbítì. Nígbà tí ìyàn líle kan mú, Jósẹ́fù dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò láti mọ̀ bóyá ọkàn wọn ti yí padà. Níkẹyìn, Jékọ́bù àti gbogbo ìdílé rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí lọ sí Íjíbítì. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta dín mẹ́wàá [290] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúráhámù.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ní Íjíbítì fún igba ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [215] tó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, wọ́n di ẹrú níbẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n bí Mósè, Ọlọ́run sì lo Mósè láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là kúrò ní Íjíbítì. Tá a bá ro gbogbo rẹ̀ pọ̀, ìtàn ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [857] ọdún la óò sọ ní Apá KEJÌ yìí.

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 11

Òṣùmàrè Àkọ́kọ́

Nígbà tó o bá rí òṣùmàrè, kí ló yẹ kó máa rán ẹ létí?

ÌTÀN 12

Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro

Inú Ọlọ́run ò dùn sí i, ìyà tó sì fi jẹ wọ́n ṣì ń pọ́n wa lójú dòní.

ÌTÀN 13

Ábúráhámù—Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run

Kí ló dé ti Ábúráhámù fi fi ilé rẹ̀ tó tura sílẹ̀ tó wá lọ lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ tó kù nínú àgọ́?

ÌTÀN 14

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Kí ló dé tí Ọlọ́run ṣe ní kí Ábúráhámù fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ?

ÌTÀN 15

Ìyàwó Lọ́ọ̀tì Bojú Wẹ̀yìn

A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú ohun tó ṣe.

ÌTÀN 16

Ísákì Rí Ìyàwó Rere Fẹ́

Kí ló mú kí Rèbékà jẹ́ ìyàwó rere? Ṣé ẹwà rẹ̀ ni àbí nǹkan míì?

ÌTÀN 17

Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra

Ísọ̀ ni Ísákì tó jẹ́ bàbá wọn fẹ́ràn jù, àmọ́ Jékọ́bù ni Rèbékà ìyá wọn fẹ́ràn jù ní tiẹ̀.

ÌTÀN 18

Jékọ́bù Lọ Sí Háránì

Léà ni Jékọ́bù kọ́kọ́ fẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé Rákélì gangan ló nífẹ̀ẹ́.

ÌTÀN 19

Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá

Ṣé orúkọ àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù náà ni wọ́n fi sọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá?

ÌTÀN 20

Dínà Kó Sínú Ìjàngbọ̀n

Àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tó yàn ló fà á.

ÌTÀN 21

Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Kórìíra Rẹ̀

Kí ló lè mú kí àwọn kan lára wọn fẹ́ pa àbúrò wọn?

ÌTÀN 22

Wọ́n Ju Jósẹ́fù Sẹ́wọ̀n

Kì í ṣe torí o ṣẹ̀ ni wọ́n ṣe jù ú sẹ́wọ̀n, torí pé ó ṣe ohun tó tọ́ ni.

ÌTÀN 23

Àwọn Àlá Fáráò

Ohun kan náà ni màlúù méje àti ṣírí ọkà méje náà túmọ̀ sí.

ÌTÀN 24

Jósẹ́fù Dán Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ Wò

Báwo ló ṣe máa mọ̀ bóyá ìwà wọn ti yí pa dà kúrò ní bó ṣe rí nígbà tí wọ́n tà á bí ẹrú?

ÌTÀN 25

Ìdílé Náà Ṣí Lọ sí Íjíbítì

Kí ló dé tó jẹ́ pé ọmọ Ísírẹ́lì ní wọ́n ń pe ìdílé Jékọ́bù dípò kí wọ́n máa pè wọ́n ní ọmọ Jékọ́bù?

ÌTÀN 26

Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọlọ́run

Jóòbù pàdánù gbogbo ohun ìní, iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ara rẹ̀ ò sì le mọ́. Ṣé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ ẹ́?

ÌTÀN 27

Ọba Búburú Kan Jẹ ní Íjíbítì

Kí ló dé tó ṣe sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí?

ÌTÀN 28

Bá a Ṣe Gba Mósè Ọmọ Ọwọ́ Là

Ìyá rẹ̀ wá ọgbọ́n dá sí ọ̀rọ̀ òfin tó sọ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.

ÌTÀN 29

Ìdí Tí Mósè Fi Sá Lọ

Mósè rò pé òun ti ṣe tán láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.

ÌTÀN 30

Igbó Tí Ń Jó

Ọlọ́run lo oríṣiríṣi iṣẹ́ ìyanu láti jẹ́ kí Mósè mọ̀ pé ó ti tó àkókò fún un láti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì.

ÌTÀN 31

Mósè àti Áárónì Lọ Rí Fáráò

Kí ló dé tí Fáráò ò gbọ́rọ̀ sí Mósè lẹ́nu pé kó dá àwọn Ísírẹ́lì sílẹ̀?

ÌTÀN 32

Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá

Ọlọ́run mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí Íjíbítì torí pé Fáráò ọba wọn ń ṣagídí, kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

ÌTÀN 33

Líla Òkun Pupa Kọjá

Mósè fi agbára Ọlọ́run pín Òkun Pupa sí méjì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn la ilẹ̀ gbígbẹ kọjá.