Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 14

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

ṢÓ O rí ohun tí Ábúráhámù fẹ́ ṣe yìí? Ọ̀bẹ ló wà lọ́wọ́ ẹ̀ yìí, ó sì dà bíi pé ọmọ rẹ̀ ló fẹ́ẹ́ pa. Kí ló dé tó fi fẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí Ábúráhámù àti Sárà ṣe rí ọmọ ọkùnrin bí ná.

Ṣó o rántí pé Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun àti Sárà máa bí ọmọkùnrin kan. Ṣùgbọ́n ìyẹn dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe, nítorí pé Ábúráhámù àti Sárà ti darúgbó gan-an. Ṣùgbọ́n o, Ábúráhámù gbà pé Ọlọ́run lè ṣe ohun tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe. Nítorí náà, kí ló ṣẹlẹ̀?

Odindi ọdún kan kọjá lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣe ìlérí yìí. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ábúráhámù pé ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tí Sárà sì jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, wọ́n bí ọmọkùnrin kan wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákì. O ò rí i pé Ọlọ́run ò gbàgbé ìlérí rẹ̀!

Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísákì dàgbà, Jèhófà dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò. Ó pè é: ‘Ábúráhámù!’ Ábúráhámù sì dáhùn pé: ‘Èmi nìyí!’ Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Mú ọmọ rẹ, Ísákì, ọmọ rẹ kan ṣoṣo, kó o sì lọ sí orí òkè kan tí èmi ó fi hàn ọ́. Nígbà tó o bá dé ibẹ̀ kó o pa á kó o sì fi rúbọ sí mi.’

Ọ̀rọ̀ yìí ba Ábúráhámù nínú jẹ́ gan-an nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ púpọ̀. Tún rántí pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé àwọn ọmọ Ábúráhámù lá máa gbé ní ilẹ̀ Kénáánì. Tí Ísákì bá wá kú, báwo ni ìyẹn ṣe máa ṣẹ? Ọ̀rọ̀ náà ò yé Ábúráhámù rárá, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ó gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu.

Nígbà tí Ábúráhámù dé orí òkè tí Ọlọ́run ní kó lọ, ó fi okùn de Ísákì ọmọ rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀ ó sì gbé e sórí pẹpẹ tó tẹ́. Ó wá yọ ọ̀bẹ tó fẹ́ fi pa á jáde. Ìgbà yẹn gan-an ni áńgẹ́lì Ọlọ́run ké sí i pé: ‘Ábúráhámù, Ábúráhámù!’ Ábúráhámù sì dáhùn pé: ‘Èmi nìyí!’

Ọlọ́run sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe ìpalára kankan fún ọmọ yẹn. Ìsinsìnyí gan-an ni mo mọ̀ pé o ní ìgbàgbọ́ nínú mi, nítorí pé o kò fi ọmọ rẹ dù mí, ìyẹn ọmọ kan ṣoṣo tó o bí.’

O ò rí i pé Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run! Ìgbàgbọ́ ẹ̀ ni pé kò sí ohun tí ò ṣeé ṣe fún Jèhófà, àti pé Jèhófà tiẹ̀ lè jí Ísákì dìde tí òun bá pa á. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gan-an pé kí Ábúráhámù pa Ísákì. Nítorí náà, Ọlọ́run mú kí àgbò kan há sáàárín igbó ṣúúrú kan nítòsí, ó sì sọ fún Ábúráhámù pé kó fi rúbọ dípò ọmọ rẹ̀.