Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 27

Ọba Búburú Kan Jẹ ní Íjíbítì

Ọba Búburú Kan Jẹ ní Íjíbítì

ÀWỌN ọkùnrin tó ò ń wò yìí ń fi agbára mú àwọn èèyàn ṣiṣẹ́. Wo ọkùnrin tó ń fi pàṣán na ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ yẹn! Àwọn ará ilé Jékọ́bù, tá à ń pè ní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ni àwọn òṣìṣẹ́ yìí. Àwọn tó ń fi agbára mú wọn ṣiṣẹ́ làwọn ará Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti di ẹrú àwọn ará Íjíbítì. Báwo ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ọ̀pọ̀ ọdún ni ìdílé Jékọ́bù, tó ti wá di ńlá báyìí, ti fi ń gbé ní àlàáfíà ní Íjíbítì. Jósẹ́fù, ẹni tó ṣe pàtàkì ní Íjíbítì tẹ̀ lé Fáráò ọba, ló ń bójú tó wọn. Ṣùgbọ́n, Jósẹ́fù ti wá kú. Fáráò tuntun kan, tí kò fẹ́ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sì ti di ọba ní Íjíbítì.

Nítorí náà, Fáráò búburú yìí sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú. Ó sì ní kí àwọn ìkà èèyàn àti òǹrorò máa ṣe alábòójútó wọn. Wọ́n fi agbára mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣe iṣẹ́ líle láti kọ́ àwọn ìlú ńlá fún Fáráò. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ńṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i. Nígbà tó ṣe, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í ba àwọn ará Íjíbítì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè di púpọ̀ jù kí wọ́n sì lágbára jù.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Fáráò ṣe? Ó bá àwọn obìnrin tó jẹ́ agbẹ̀bí fún àwọn obìnrin Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá ń bímọ sọ̀rọ̀, ó wí pé: ‘Ṣe ni kẹ́ ẹ máa pa gbogbo ọmọ ọkùnrin tí wọ́n bá bí.’ Ṣùgbọ́n ẹni rere ni àwọn obìnrin wọ̀nyí, wọn ò sì jẹ́ pa àwọn ọmọ àṣẹ̀ṣẹ̀bí náà.

Nítorí náà, Fáráò pàṣẹ fún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ pé: ‘Ẹ máa pa gbogbo ọmọkùnrin táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Ṣùgbọ́n ẹ máa dá àwọn ọmọbìnrin wọn sí.’ Àṣẹ yẹn ò ha ti burú jù bí? Jẹ́ ká wo bá a ṣe gba ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin náà là.