Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 19

Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá

Jékọ́bù Ní Ìdílé Ńlá

ÌWỌ wo ìdílé ńlá yìí ná. Àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Jékọ́bù bí nìwọ̀nyí. Ó sì ní àwọn ọmọbìnrin pẹ̀lú. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yìí? Jẹ́ ká mọ díẹ̀ nínú wọn.

Léà bí Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì, àti Júdà. Nígbà tí Rákélì rí i pé òun ò bí ọmọ kankan, inú ẹ̀ bà jẹ́ gidigidi. Nítorí náà, ó fi Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Jékọ́bù, Bílíhà sì bí ọmọkùnrin méjì, Dánì àti Náfútálì. Ni Léà náà bá fi Sílípà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Jékọ́bù, Sílípà sì bí Gádì àti Áṣérì. Níkẹyìn, Léà tún bí ọmọ méjì sí i, Ísákárì àti Sébúlúnì.

Nígbà tó yá, Rákélì bí ọmọ kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jósẹ́fù. Tó bá yá, a óò gbọ́ púpọ̀ sí i nípa Jósẹ́fù, nítorí ó di èèyàn ńlá. Àwọn ọmọkùnrin mọ́kànlá wọ̀nyí ni Jékọ́bù bí nígbà tó ń gbé lọ́dọ̀ Lábánì bàbá Rákélì.

Jékọ́bù tún bí àwọn ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n ọ̀kan péré ni Bíbélì dárúkọ rẹ̀. Dínà ló ń jẹ́.

Nígbà tó yá, Jékọ́bù pinnu láti fi Lábánì sílẹ̀ kó sì padà lọ sí Kénáánì. Nítorí náà, ó kó gbogbo ọmọ àti ìyàwó rẹ̀ àti agbo àgùntàn ńlá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn náà.

Nígbà tó ṣe díẹ̀ tí Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ ti padà dé sí Kénáánì, Rákélì bí ọmọkùnrin mìíràn. Ó bí ọmọ yìí nígbà tí wọ́n ń lọ ìrìn àjò kan. Kò rọrùn rárá fún Rákélì láti bí ọmọ yìí, ṣe ló kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà tó ń rọbí. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin jòjòló tó bí kò kú. Jékọ́bù pe orúkọ ọmọ náà ní Bẹ́ńjámínì.

Ó yẹ ká rántí orúkọ àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Jékọ́bù bí nítorí pé ọ̀dọ̀ wọn ni odindi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ wá. Orúkọ mẹ́wàá nínú àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù àti orúkọ ọmọ méjì tí Jósẹ́fù bí la fi ń pe àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì. Ísákì lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé lẹ́yìn tí Jékọ́bù bí àwọn ọmọ wọ̀nyí, ó sì dájú pé inú Ísákì ti ní láti dùn gidigidi pé òun ní ọ̀pọ̀ ọmọ-ọmọ. Ṣùgbọ́n jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà ọmọ-ọmọ rẹ̀ obìnrin.