Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 30

Igbó Tí Ń Jó

Igbó Tí Ń Jó

MÓSÈ rin ìrìn ọ̀nà jíjìn wá sí Òkè Hórébù láti wá koríko tútù fún àwọn àgùntàn rẹ̀. Ibẹ̀ ló ti rí igbó kan tí iná ń jó nínú rẹ̀ àmọ́ tí igbó náà kò jó!

Mósè ronú pé: ‘Àrà mérìíyìírí ni èyí. Màá sún mọ́ ọn láti wò ó dáadáa.’ Nígbà tó sún mọ́ ọn, ó gbọ́ ohùn kan láti àárín igbó náà tó wí pé: ‘Má ṣe kọjá ibi tó o wà yẹn. Bọ́ sálúbàtà ẹsẹ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tó o dúró sí yìí.’ Ọlọ́run ló ń gba ẹnu áńgẹ́lì kan sọ̀rọ̀, nítorí náà Mósè bo ojú rẹ̀.

Ọlọ́run wá sọ pé: ‘Mo ti rí bí àwọn èèyàn mi ṣe ń jìyà ní Íjíbítì. Nítorí náà màá dá wọn sílẹ̀, ìwọ ni màá sì rán láti kó àwọn èèyàn mi jáde kúrò ní Íjíbítì.’ Jèhófà fẹ́ kó àwọn èèyàn rẹ̀ wá sí ilẹ̀ Kénáánì dáradára náà.

Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé: ‘Èmi tí mi ò já mọ́ nǹkan kan. Báwo ni mo ṣe máa ṣe é? Ká ní mo tiẹ̀ lọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á sọ fún mi pé, “Ta ló rán ọ?” Kí ni màá wá sọ?’

Ọlọ́run dáhùn pé: ‘Ohun tí wàá sọ rèé: ‘“JÈHÓFÀ Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù ni ó rán mi sí yín.”’ Jèhófà sì fi kún un pé: ‘Èyí ni orúkọ mi títí láé.’

Mósè fèsì pé, ‘Tí wọn ò bá gbà mí gbọ́ nígbà tí mo bá sọ fún wọn pé ìwọ lo rán mi ńkọ́?’

Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí ló wà lọ́wọ́ rẹ yẹn?’

Mósè dáhùn pé: ‘Ọ̀pá ni.’

Ọlọ́run wí fún un pé: ‘Jù ú sílẹ̀.’ Nígbà tí Mósè sì jù ú sílẹ̀, ọ̀pá náà di ejò. Lẹ́yìn èyí, Jèhófà fi iṣẹ́ ìyanu mìíràn han Mósè. Ó sọ fún un pé: ‘Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ ẹ̀wù rẹ.’ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tó sì yọ ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó funfun bíi yìnyín! Ṣe ni ọwọ́ náà dà bí èyí tí àrùn búburú tá à ń pè ní ẹ̀tẹ̀ ti bò. Lẹ́yìn èyí, Jèhófà fún Mósè ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu kẹta. Ní òpin rẹ̀ ó sọ fún un pé: ‘Nígbà tó o bá ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò gbà pé èmi ni ó rán ọ.’

Lẹ́yìn náà, Mósè lọ sí ilé ó sì sọ fún Jẹ́tírò pé: ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà lọ sọ́dọ̀ àwọn ará mi ní Íjíbítì kí n lọ wo àlàáfíà wọn.’ Nítorí náà, Mósè dágbére fún Jẹ́tírò, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ padà sí Íjíbítì.