ÌTÀN 12
Àwọn Èèyàn Kọ́ Ilé Gogoro
Ọ̀PỌ̀ ọdún ti kọjá. Àwọn ọmọ Nóà ti bí ọmọ rẹpẹtẹ. Àwọn ọmọ tiwọn náà sì tún bí ọ̀pọ̀ ọmọ sí i nígbà tí wọ́n dàgbà. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn èèyàn di púpọ̀ láyé.
Ọ̀kan nínú àwọn èèyàn wọ̀nyí ni ọmọ-ọmọ ọmọ Nóà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nímírọ́dù. Èèyàn búburú ni Nímírọ́dù, ó máa ń dọdẹ ẹranko àtèèyàn ó sì máa ń pa wọ́n. Nímírọ́dù tún sọ ara rẹ̀ di ọba lórí àwọn èèyàn tó kù. Inú Ọlọ́run kò dùn sí Nímírọ́dù.
Èdè kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn máa ń sọ nígbà náà. Nímírọ́dù fẹ́ kí gbogbo wọn wà lójú kan kó lè máa jọba lé wọn lórí. Nítorí náà, ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe? Ó sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n dá ìlú ńlá kan sílẹ̀ kí wọ́n sì kọ́ ilé gogoro sínú rẹ̀. Bíríkì tí wọ́n máa fi kọ́ ilé náà lò ń wò tí wọ́n ń mọ nínú àwòrán yìí.
Inú Jèhófà Ọlọ́run ò dùn sí ilé tí wọ́n ń kọ́ yìí. Ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn náà tú ká kí wọ́n sì máa gbé ibi gbogbo láyé. Ṣùgbọ́n ohun táwọn èèyàn náà sọ ni pé: ‘Ẹ wá! Ẹ jẹ́ ká dá ìlú ńlá kan sílẹ̀ ká sì mọ ilé gogoro kan tí orí rẹ̀ yóò kan ọ̀run. Àwa yóò sì di olókìkí!’ Ara wọn ni àwọn èèyàn náà fẹ́ fi èyí gbé ga kì í ṣe Ọlọ́run.
Nítorí náà, Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣíwọ́ kíkọ́ ilé gogoro náà. Ǹjẹ́ o mọ bó ṣe ṣe é? Ó mú kí àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè lójijì, dípò kí wọ́n máa sọ èdè kan ṣoṣo. Ni àwọn mọlé-mọlé ò bá gbọ́ èdè ara wọn mọ́. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe orúkọ ìlú náà ní Bábélì, tàbí Bábílónì, èyí tó túmọ̀ sí “Ìdàrúdàpọ̀.”
Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi Bábélì sílẹ̀. Àwọn tí wọ́n bá rí i pé àwọn gbọ́ èdè ara àwọn á kóra jọ, wọ́n á sì lọ máa gbé apá ibòmíràn ní ayé.