Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 16

Ísákì Rí Ìyàwó Rere Fẹ́

Ísákì Rí Ìyàwó Rere Fẹ́

ǸJẸ́ o mọ obìnrin tó wà nínú àwòrán yìí? Rèbékà ni orúkọ rẹ̀. Ọkùnrin tó fẹ́ lọ pàdé ni Ísákì. Obìnrin yìí ni yóò di ìyàwó Ísákì. Báwo ni èyí ṣe ṣẹlẹ̀?

Bó ṣe jẹ́ rèé: Ábúráhámù fẹ́ fẹ́ ìyàwó rere fún Ísákì ọmọ rẹ̀. Kò fẹ́ kí Ísákì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin Kénáánì, nítorí ọlọ́run èké làwọn èèyàn yẹn ń sìn. Nítorí náà, Ábúráhámù pe ìránṣẹ́ rẹ̀ ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ kó o padà lọ sí ibi tí àwọn ìbátan mi ń gbé ní Háránì kó o sì wá ìyàwó wá fún Ísákì ọmọ mi.’

Ojú ẹsẹ̀ ni ìránṣẹ́ Ábúráhámù kó ràkúnmí mẹ́wàá tó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò jíjìn náà. Nígbà tó dé tòsí ibi tí àwọn ìbátan Ábúráhámù ń gbé, ó dúró ní ibi kànga kan. Ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ló débẹ̀, àkókò tí àwọn obìnrin ìlú yẹn máa ń jáde láti wá pọn omi nínú kànga náà ni. Nítorí náà, ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jẹ́ kí obìnrin tó bá fún èmi àti àwọn ràkúnmí wọ̀nyí ní omi mu jẹ́ ẹni tí ìwọ yàn láti jẹ́ aya Ísákì.’

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Rèbékà dé láti pọn omi. Nígbà tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù tọrọ omi lọ́wọ́ rẹ̀, ó fún un ní omi. Ẹ̀yìn ìgbà náà ló tún pọn omi tí ó tó fún gbogbo àwọn ràkúnmí rẹ̀ tí òùngbẹ ti ń gbẹ. Iṣẹ́ ńlá gan-an ló ṣe nítorí pé ràkúnmí máa ń mu omi gan-an.

Nígbà tí Rèbékà ṣe èyí tán, ìránṣẹ́ Ábúráhámù béèrè orúkọ bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó tún béèrè bóyá òun lè ríbi sùn mọ́jú ní ilé wọn. Rèbékà wí pé: ‘Bẹ́túélì ni orúkọ bàbá mi, àyè sì wà láti sùn ní ilé wa.’ Ìránṣẹ́ Ábúráhámù mọ̀ pé ọmọ Náhórì ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù ni Bẹ́túélì. Nítorí náà, ó kúnlẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe darí òun sí àwọn ìbátan Ábúráhámù.

Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn ni ìránṣẹ́ Ábúráhámù sọ ìdí tí òun fi wá fún Bẹ́túélì níṣojú Lábánì ẹ̀gbọ́n Rèbékà. Àwọn méjèèjì gbà pé kí Rèbékà bá a lọ láti fẹ́ Ísákì. Kí ni Rèbékà wí nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé yóò bá ìránṣẹ́ Ábúráhámù lọ? Ó wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ pé ó wu òun láti lọ. Nítorí náà, ọjọ́ kejì gan-an ni wọ́n gun ràkúnmí tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn náà padà lọ sí Kénáánì.

Ìgbà tí wọ́n dé ọ̀hún, alẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lẹ́. Rèbékà rí ọkùnrin kan tó ń rìn kiri nínú oko. Ísákì ni. Inú Ísákì dùn láti rí Rèbékà. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọdún mẹ́ta sẹ́yìn báyìí ni tí Sárà ìyá Ísákì kú, èyí ṣì ń dun Ísákì títí di àkókò yẹn. Àmọ́ ní báyìí, Ísákì ní ìfẹ́ Rèbékà gan-an, inú rẹ̀ sì padà dùn.