Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 17

Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra

Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra

ÀWỌN ọmọdékùnrin méjì tó wà nínú àwòrán yìí ò jọra wọn, àbí wọ́n jọra? Ǹjẹ́ o mọ orúkọ wọn? Orúkọ èyí tó jẹ́ ọdẹ ni Ísọ̀, orúkọ èyí tó ń tọ́jú àgùntàn sì ń jẹ́ Jékọ́bù.

Ísọ̀ àti Jékọ́bù yìí ni ìbejì tí Ísákì àti Rèbékà bí. Ísákì, tó jẹ́ bàbá wọn, fẹ́ràn Ísọ̀ gan-an nítorí pé ó mọ ọdẹ ṣe, ó sì máa ń pata sí ìdílé wọn lẹ́nu. Ṣùgbọ́n, Jékọ́bù ni Rèbékà fẹ́ràn jù nítorí tó jẹ́ ọmọ jẹ́jẹ́, tí kì í ṣe ìjàngbọ̀n.

Ábúráhámù tó jẹ́ bàbá bàbá wọn ṣì wà láàyè, a lè fojú inú wo bí Jékọ́bù á ṣe máa fẹ́ láti fetí sílẹ̀ gbọ́ bó ti ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Nígbà tó yá, Ábúráhámù kú ní ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] nígbà tí àwọn ìbejì náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

Nígbà tí Ísọ̀ pé ọmọ ogójì [40] ọdún, ó gbé obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kénáánì níyàwó. Èyí ba Ísákì àti Rèbékà nínú jẹ́ gidigidi nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà.

Ó wá di ọjọ́ kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí inú bí Ísọ̀ gidigidi sí Jékọ́bù tí wọ́n bí ṣìkejì rẹ̀. Àkókò tó tí Ísákì yóò súre fún ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà. Níwọ̀n bí Ísọ̀ ti ju Jékọ́bù lọ, Ísọ̀ retí pé òun ni yóò gba ìre tàbí ìbùkún yìí. Ṣùgbọ́n ṣáájú àkókò yìí ni Ísọ̀ ti ta ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti gba ìbùkún náà fún Jékọ́bù. Àti pé, nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì, Ọlọ́run ti sọ pé Jékọ́bù ni yóò gba ìbùkún náà. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyí. Ísákì súre fún Jékọ́bù ọmọ rẹ̀.

Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ nípa èyí, inú bí i gidigidi sí Jékọ́bù. Inú bí i gan-an tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé pípa lòun máa pa Jékọ́bù. Nígbà tí Rèbékà gbọ́, ẹ̀rù bà á gidigidi. Nítorí náà, ó sọ fún Ísákì ọkọ rẹ̀ pé: ‘Á burú púpọ̀ bí Jékọ́bù pẹ̀lú bá lọ gbé ọ̀kan lára àwọn obìnrin Kénáánì wọ̀nyí níyàwó.’

Nítorí èyí, Ísákì pe Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ ó sì wí fún un pé: ‘Má ṣe fẹ́ ìyàwó láàárín àwọn ọmọ Kénáánì o. Ńṣe ni kó o lọ sí ilé Bẹ́túélì bàbá ìyá rẹ ní Háránì. Kó o fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Lábánì ọmọ rẹ̀.’

Jékọ́bù gbọ́ ti bàbá rẹ̀, ojú ẹsẹ̀ ló sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò jíjìn lọ sí ibi táwọn ìbátan ẹ̀ ń gbé ní Háránì.