Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 24

Jósẹ́fù Dán Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ Wò

Jósẹ́fù Dán Àwọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ Wò

JÓSẸ́FÙ fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́wàá ṣì jẹ́ ìkà àti aláìláàánú. Nítorí náà, ó wí pé: ‘Amí ni yín. Ńṣe lẹ wá wo ibi tẹ́ ẹ ti lè rí ìlú wa mú.’

Wọ́n dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa kì í ṣe amí. Olóòótọ́ èèyàn ni wá. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni gbogbo wa. Méjìlá ni wá. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú wa kò sí mọ́, èyí àbíkẹ́yìn sì wà ní ilé lọ́dọ̀ bàbá wa.’

Jósẹ́fù ṣe bí ẹni pé kò gbà wọ́n gbọ́. Ó fi èyí tó ń jẹ́ Síméónì sátìmọ́lé, ó sì jẹ́ káwọn yòókù kó oúnjẹ lọ sí ilé. Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: ‘Tẹ́ ẹ bá ń padà bọ̀, ẹ gbọ́dọ̀ mú èyí tẹ́ ẹ pè ní àbúrò yín àbíkẹ́yìn wá pẹ̀lú yín.’

Nígbà tí wọ́n padà dé ilé ní Kénáánì, wọ́n sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jékọ́bù bàbá wọn. Inú Jékọ́bù bà jẹ́ gidigidi. Ó kígbe pé: ‘Jósẹ́fù kò sí mọ́, Síméónì kò tún sí mọ́ nísinsìnyí. Èmi ò ní jẹ́ kẹ́ ẹ mú Bẹ́ńjámínì àbíkẹ́yìn mi lọ o.’ Ṣùgbọ́n nígbà tí oúnjẹ wọn ń tán lọ, ó di dandan fún Jékọ́bù kó jẹ́ kí wọ́n mú Bẹ́ńjámínì lọ sí Íjíbítì kí wọ́n lè rí oúnjẹ rà sí i.

Jósẹ́fù rí i tí àwọn arákùnrin rẹ̀ ń bọ̀. Inú rẹ̀ dùn púpọ̀ láti rí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ìyà rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹnì kan nínu wọn tó mọ̀ pé Jósẹ́fù ni ẹni pàtàkì yìí. Jósẹ́fù wá ṣe nǹkan kan láti dán àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ mẹ́wàá wò.

Ó ní kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ di oúnjẹ kún inú gbogbo àpò wọn. Ṣùgbọ́n láìjẹ́ kí wọ́n mọ̀, ó tún ní kí wọ́n fi ife fàdákà òun sínú àpò Bẹ́ńjámínì. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti lọ tí wọ́n sì ti rìn jìnnà díẹ̀, Jósẹ́fù rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n sáré tẹ̀ lé wọn. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lé wọn bá, wọ́n wí pé: ‘Èé ṣe tí ẹ fi jí ife fàdákà ọ̀gá wa?’

Gbogbo wọn dáhùn pé: ‘Àwa ò jí ife o. Bẹ́ ẹ bá rí ife náà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wa, pípa ni kẹ́ ẹ pa olúwarẹ̀.’

Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í tú gbogbo àpò wọn, wọ́n sì rí ife náà nínú àpò Bẹ́ńjámínì, gẹ́gẹ́ bó o ti ń wò ó nínú àwòrán yìí. Àwọn ìránṣẹ́ náà wí pé: ‘Gbogbo ẹ̀yin tó kù lè máa lọ, ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé wa.’ Kí ni àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ mẹ́wàá yòókù máa wá ṣe báyìí o?

Gbogbo wọn ló bá Bẹ́ńjámínì padà sí ilé Jósẹ́fù. Jósẹ́fù wí fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: ‘Gbogbo yín lè máa lọ sí ilé, ṣùgbọ́n Bẹ́ńjámínì gbọ́dọ̀ dúró níhìn-ín, kó máa ṣe ẹrú mi.’

Júdà wá sọ̀rọ̀, ó wí pé: ‘Bí mo bá padà sí ilé láì mú ọmọ yìí dání, bàbá mi yóò kú nítorí ó fẹ́ràn ọmọ náà gidigidi. Nítorí náà, jọ̀wọ́, fi èmi ṣe ẹrú rẹ, kó o sì jẹ́ kí ọmọ yìí máa lọ sí ilé.’

Jósẹ́fù wá rí i báyìí pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti yíwà padà. Wọn kì í ṣe ìkà àti aláìláàánú mọ́. Jẹ́ ká wá wo ohun tí Jósẹ́fù ṣe.