Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 3

Láti Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì sí Àkókò Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Láti Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì sí Àkókò Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ìgbèkùn ní Íjíbítì wá sí Òkè Sínáì, níbi tí Ọlọ́run ti fún wọn ní àwọn òfin rẹ̀. Nígbà tó ṣe, Mósè rán ọkùnrin méjìlá láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì. Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn mú ìròyìn búburú padà wá. Wọ́n mú kí àwọn èèyàn náà fẹ́ láti padà lọ sí Íjíbítì. Nítorí àìní ìgbàgbọ́ wọn, Ọlọ́run jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyà nípa mímú kí wọ́n máa rìn káàkiri fún ogójì [40] ọdún ní aginjù.

Níkẹyìn, Ọlọ́run yan Jóṣúà láti ṣe aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ilẹ̀ náà, Jèhófà mú kí àwọn iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀. Ó mú kí Odò Jọ́dánì má ṣàn mọ́, ó mú kí odi Jẹ́ríkò wó lulẹ̀, ó sì mú kí oòrùn dúró sójú kan fún odindi ọjọ́ kan. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà, wọ́n gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Kénáánì.

Bá a bá bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jóṣúà, ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [356] ọdún làwọn onídàájọ́ fi ṣàkóso Ísírẹ́lì. A óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀pọ̀ nínú wọn, títí kan Bárákì, Gídíónì, Jẹ́fútà, Sámúsìnì àti Sámúẹ́lì. A ó sì tún kà nípa àwọn obìnrin bíi Ráhábù, Dèbórà, Jáẹ́lì, Rúùtù, Náómì àti Dèlílà. Ní àkópọ̀, ìtàn irínwó ọdún ó dín mẹ́rin [396] ló wà ní Apá KẸTA.

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 34

Irú Oúnjẹ Tuntun Kan

Oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run pèsè yìí ń rọ̀ láti ọ̀run.

ÌTÀN 35

Jèhófà Fún Wọn Ní Òfin Rẹ̀

Òfin méjì wo ló tóbi ju Òfin Mẹ́wàá lọ?

STORY 36

Ère Ọmọ Màlúù Oníwúrà

Kí ló mú kí àwọn èèyàn máa bọ ère tí wọ́n fi yẹtí ṣe?

ÌTÀN 37

Àgọ́ Kan Fún Ìjọsìn

Inú yàrá inú lọ́hùn-ún ní àpótí májẹ̀mú máa ń wà.

ÌTÀN 38

Àwọn Amí Méjìlá

Mẹ́wàá lára àwọn amí náà sọ ohun kan náà, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ohun tí àwọn méjì sọ. Ta ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbọ́?

ÌTÀN 39

Ọ̀pá Áárónì Yọ Òdòdó

Báwo ni igi gbígbẹ kan ṣe lè mú òdòdó jáde, kó sì so èso ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo?

ÌTÀN 40

Mósè Lu Àpáta

Ohun tí Mósè fẹ́ ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ Mósè múnú bí Jèhófà.

ÌTÀN 41

Ejò Bàbà

Kí ló dé tí Ọlọ́run ṣe rán àwọn ejò olóró láti ṣán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ?

ÌTÀN 42

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kan Sọ̀rọ̀

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù rí ohun kan tí Báláámù ò lè rí.

ÌTÀN 43

Jóṣúà Di Aṣáájú

Kí ló dé tí wọ́n ṣe fi Jóṣúà rọ́pò Mósè, nígbà tó jẹ́ pé Mósè ṣì lágbára?

ÌTÀN 44

Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

Báwo ni Ráhábù ṣe ran àwọn ọkùnrin méjì náà lọ́wọ́, kí ló sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe?

ÌTÀN 45

Bí Wọ́n Ṣe La Odò Jọ́dánì Kọjá

Iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn àlùfáà náà gbẹ́sẹ̀ sínú omi.

ÌTÀN 46

Odi Jẹ́ríkò

Báwo ni okùn kan lásán ṣe lè mú kí ògiri máà wó?

ÌTÀN 47

Olè Kan Ní Ísírẹ́lì

Ṣé ọkùnrin búburú kan ṣoṣo lè fa wàhálà bá gbogbo orílẹ̀-èdè?

ÌTÀN 48

Àwọn Ará Gíbéónì Ọlọgbọ́n

Wọ́n tan Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá wọn dá májẹ̀mú, àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àdéhùn wọn mọ́.

ÌTÀN 49

Oòrùn Dúró Sójú Kan

Jèhófà ṣe ohun kan fún Jóṣúà tí kò ṣe rí, tí kò sì tún ṣe látìgbà yẹn.

ÌTÀN 51

Rúùtù Àti Náómì

Rúùtù fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ kò lè máa bá Náómì gbé, kó sì máa sin Jèhófà.

ÌTÀN 52

Gídíónì Àti Ọ̀ọ́dúnrún Ọkùnrin Rẹ̀

Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ kan ni Ọlọ́run gbà yan àwọn kéréje tó máa lọ sí ojú ogun, bí wọn ṣe mu omi ló lò.

ÌTÀN 53

Ìlérí Jẹ́fútà

Kì í ṣe òun nìkan ni ìlérí tó ṣe fún Jèhófà kàn, ó tún kan ọmọbìnrin rẹ̀.

ÌTÀN 54

Ọkùnrin Tó Lágbára Jù Lọ

Báwo ni Dèlílà ṣe mọ àṣírí agbára Sámúsìnì?

ÌTÀN 55

Ọmọkùnrin Kékeré Kan Sin Ọlọ́run

Ọlọ́run rán Sámúẹ́lì ní iṣẹ́ kan tó le sí Élì, Wòlíì Àgbà.