Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 37

Àgọ́ Kan Fún Ìjọsìn

Àgọ́ Kan Fún Ìjọsìn

ǸJẸ́ o mọ ohun tí ilé yìí jẹ́? Ilé yìí ni àgọ́ pàtàkì kan tí wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà. Orúkọ tí wọ́n tún máa ń pè é ní àgọ́ ìjọsìn. Àwọn èèyàn náà parí kíkọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó mú èrò pé kí wọ́n kọ́ ilé náà wá?

Jèhófà lẹni tó mú èrò pé kí wọ́n kọ́ ilé náà wá. Nígbà tí Mósè wà lórí Òkè Sínáì, Jèhófà sọ bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ náà fún un. Ó sọ pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ náà lọ́nà tó máa fi rọrùn-ún tú palẹ̀. Nípa báyìí, wọ́n á lè gbé àtúpalẹ̀ àgọ́ náà lọ sí ibòmíràn kí wọ́n sì tún tò ó pọ̀ níbẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn, nínú aginjù, wọ́n ń gbé àgọ́ náà kiri.

Bó o bá wo inú yàrá kékeré tó wà ní ìkángun àgọ́ yìí, wàá rí àpótí kan níbẹ̀. Èyí ni wọ́n ń pè ní àpótí ẹ̀rí. Ó ní àwọn áńgẹ́lì tàbí kérúbù méjì tí wọ́n fi wúrà ṣe, ọ̀kan lápá ọ̀tún àti èkejì lápá òsì. Ọlọ́run tún Òfin Mẹ́wàá náà kọ sára òkúta pẹlẹbẹ méjì, nítorí pé Mósè ti fọ́ àwọn òkúta méjì àkọ́kọ́. Wọ́n sì tọ́jú àwọn òkúta wọ̀nyí sínú àpótí ẹ̀rí náà. Wọ́n tún tọ́jú àwo mánà kan sínú rẹ̀. Ǹjẹ́ o rántí ohun tí mánà jẹ́?

Áárónì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè ni Jèhófà yàn ní àlùfáà àgbà. Òun ló ń ṣáájú àwọn èèyàn ní jíjọ́sìn Jèhófà. Àlùfáà sì làwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú.

Wá wo yàrá tó tóbi jù nínú àgọ́ náà. Ó tó ìlọ́po méjì yàrá kékeré náà. Ṣó o rí àpótí tí èéfín ń rú jáde lórí rẹ̀ yẹn? Pẹpẹ tí àwọn àlùfáà ti ń sun ohun olóòórùn dídùn tó ń jẹ́ tùràrí nìyẹn. Lẹ́yìn náà, wàá tún rí ọ̀pá fìtílà tó ní fìtílà méje lórí. Ohun kẹta tó sì wà nínú yàrá náà ni tábìlì. Orí rẹ̀ ni wọ́n máa ń tọ́jú ìṣù àkàrà méjìlá sí.

Nínú àgbàlá àgọ́ náà, agbada ńlá kan wà níbẹ̀, tí omi kún inú rẹ̀. Àwọn àlùfáà máa ń fi omi yìí wẹ̀. Pẹpẹ ńlá sì tún wà níbẹ̀. Orí pẹpẹ yìí ni wọ́n ti máa ń fi iná sun àwọn ẹran tí wọ́n bá pa rúbọ sí Jèhófà. Àgọ́ náà wà láàárín ibùdó tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé.