Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 52

Gídíónì Àti Ọ̀ọ́dúnrún Ọkùnrin Rẹ̀

Gídíónì Àti Ọ̀ọ́dúnrún Ọkùnrin Rẹ̀

ǸJẸ́ o rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níhìn-ín? Àwọn jagunjagun Ísírẹ́lì ni gbogbo àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. Omi làwọn tó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ yẹn ń mu. Gídíónì Onídàájọ́ ló dúró nítòsí wọn yẹn. Ó ń wo bí wọ́n ṣe ń mu omi.

Túbọ̀ kíyè sí oríṣiríṣi ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin náà gbà ń mu omi. Ojú làwọn kan da dé omi. Ṣùgbọ́n ẹnì kan ń fi ọwọ́ bu omi sẹ́nu, kó lè máa kíyè sí ohun tí ń lọ láyìíká rẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì, nítorí Jèhófà ti sọ fún Gídíónì pé kìkì àwọn ọkùnrin tó bá ń ṣọ́nà nígbà tí wọ́n bá ń mu omi ni kó yàn. Ọlọ́run sọ pé kó dá àwọn tó kù padà sílé. Jẹ́ ká wo ìdí rẹ̀.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ti kó sínú wàhálà. Ohun tó fà á ni pé wọn ò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Àwọn ará Mídíánì ti di alágbára lórí wọn, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n. Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, Jèhófà sì gbọ́ igbe wọn.

Jèhófà sọ fún Gídíónì pé kó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ, nítorí náà Gídíónì kó ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n [32,000] àwọn jagunjagun jọ. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé márùndínlógójì [135,000] àwọn jagunjagun ló fẹ́ bá Ísírẹ́lì jà. Síbẹ̀, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Àwọn ọmọ ogun rẹ ti pọ̀ jù.’ Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ìdí ni pé tí Ísírẹ́lì bá lọ ṣẹ́gun, wọ́n lè máa rò pé àwọn làwọ́n fúnra àwọn ṣẹ́gun. Wọ́n lè máa rò pé àwọn ò nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti ṣẹ́gun. Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Sọ fún gbogbo àwọn tó bá ń bẹ̀rù pé kí wọ́n padà sílé.’ Nígbà tí Gídíónì sọ bẹ́ẹ̀ tán, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] nínú àwọn jagunjagun rẹ̀ ló padà sílé. Ó wá ku kìkì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] èèyàn péré láti bá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé márùndínlógójì [135,000] jagun.

Tún gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ: ‘Àwọn èèyàn ẹ yìí ṣì pọ̀ jù.’ Nítorí náà, ó sọ fún Gídíónì pé kó jẹ́ káwọn èèyàn náà mu omi nínú odò kékeré yìí kó sì dá gbogbo àwọn tó bá dojú dé omi láti mumi padà sí ilé. Jèhófà ṣèlérí pé: ‘Màá mú kó o ṣẹ́gun pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin tí wọ́n ń ṣọ́nà nígbà tí wọ́n ń mu omi.’

Nígbà tí àkókò ìjà tó. Gídíónì pín àwọn ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkùnrin rẹ̀ sí ọ̀nà mẹ́ta. Ó fún olúkúlùkù wọn ní ìwo kọ̀ọ̀kan, àti ìṣà kọ̀ọ̀kan tó ní ògùṣọ̀ nínú. Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, gbogbo wọn kóra jọ yí àgọ́ àwọn jagunjagun ọ̀tá ká. Nígbà tó yá, lẹ́ẹ̀kan náà, gbogbo wọn fun ìpè wọn, wọ́n sì fọ́ ìṣà wọn mọ́lẹ̀, wọ́n sì kígbe pé: ‘Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!’ Nígbà táwọn jagunjagun ọ̀tá jí, wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, jìnnìjìnnì sì bò wọ́n. Gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ, báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun nìyẹn.