ÌTÀN 38
Àwọn Amí Méjìlá
WO ÈSO táwọn ẹni yìí ń gbé. Wo bí ìdì èso náà ti tóbi tó. Géńdé méjì ló fọ̀pá gbé e. Sì wo àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì tó wà ńbẹ̀. Ibo làwọn èso dáradára wọ̀nyí ti wá? Láti ilẹ̀ Kénáánì ni. Ṣó o rántí pé Kénáánì ni ibi tí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ń gbé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí ìyàn tó mú níbẹ̀, Jékọ́bù àti ìdílé rẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì. Nísinsìnyí, ní nǹkan bí igba ọdún ó lé mẹ́rìndínlógún [216] lẹ́yìn náà, Mósè tún ń ṣáájú àwọn èèyàn náà padà lọ sí Kénáánì. Wọ́n ti dé ibì kan tó ń jẹ́ Kádéṣì nínú aginjù náà.
Àwọn èèyàn búburú ló ń gbé ilẹ̀ Kénáánì. Nítorí náà, Mósè rán àwọn amí méjìlá jáde, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ wo iye àwọn tí ń gbé ibẹ̀, àti bí wọ́n ṣe lágbára tó. Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà bá dára fún nǹkan ọ̀gbìn. Ẹ sì rí i pé ẹ mú lára èso ilẹ̀ náà bọ̀.’
Nígbà tí àwọn amí náà padà dé sí Kádéṣì, wọ́n jábọ̀ fún Mósè pé: ‘Ilẹ̀ dáradára gan-an ni.’ Wọ́n fi díẹ̀ lára àwọn èso ilẹ̀ náà han Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ṣùgbọ́n mẹ́wàá lára àwọn amí náà wí pé: ‘Àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìlú náà tóbi wọ́n sì lágbára. Wọ́n á pa wá bá a bá dán an wò láti gba ilẹ̀ wọn.’
Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n wí pé: ‘Ì bá sàn ká ti kú sí Íjíbítì tàbí sínú aginjù níhìn-ín pàápàá. Wọ́n á pa wá nínú ogun, wọ́n á sì kó àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ẹ jẹ́ ká yan aṣáájú tuntun rọ́pò Mósè, ká sì padà sí Íjíbítì!’
Ṣùgbọ́n méjì nínú àwọn amí náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì gbìyànjú láti fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀. Orúkọ wọn ni Jóṣúà àti Kálébù. Wọ́n wí pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Jèhófà wà pẹ̀lú wa. Kò ní ṣòro láti gba ilẹ̀ náà.’ Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà kò fetí sílẹ̀. Àní wọ́n tiẹ̀ fẹ́ pa Jóṣúà àti Kálébù pàápàá.
Èyí mú kí Jèhófà bínú gidigidi, ó sì wí fún Mósè pé: ‘Kò sí ọ̀kan nínú àwọn èèyàn náà láti ọmọ ogún ọdún lọ sókè tó máa wọ ilẹ̀ Kénáánì. Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ti ṣe ní Íjíbítì àti ní aginjù, síbẹ̀ wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé mi. Nítorí náà, ṣe ni wọ́n á máa rìn kiri nínú aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo wọn fi máa kú. Kìkì Jóṣúà àti Kálébù nìkan ló máa wọ ilẹ̀ Kénáánì.’