Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 43

Jóṣúà Di Aṣáájú

Jóṣúà Di Aṣáájú

MÓSÈ fẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì. Nítorí náà, ó sọ pé: ‘Jèhófà, jẹ́ kí n ré Odò Jọ́dánì kọjá, kí n lè rí ilẹ̀ dáradára náà.’ Ṣùgbọ́n Jèhófà wí pé: ‘Ó tó! Má ṣe tún mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí mọ́!’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi sọ bẹ́ẹ̀?

Nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Mósè lu àpáta ni. Ṣó o rántí pé òun àti Áárónì kò fi ọlá fún Jèhófà. Wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé Jèhófà ló mú omi wá látinú àpáta. Fún ìdí yìí, Jèhófà sọ pé òun ò ní jẹ́ kí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì.

Nítorí náà, ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Áárónì kú, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Mú Jóṣúà, kó o sì mú un dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti níwájú àwọn èèyàn náà. Níwájú gbogbo wọn, sọ fún wọn pé Jóṣúà ni aṣáájú wọn tuntun.’ Mósè ṣe bí Jèhófà ti wí gan-an, gẹ́gẹ́ bó o ṣe lè rí i nínú àwòrán yìí.

Ìgbà náà ni Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: ‘Ṣe bí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni, kó o má sì bẹ̀rù. Ìwọ lo máa ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì tí mo ti ṣèlérí fún wọn, màá sì wà pẹ̀lú rẹ.’

Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé kó gun òkè lọ sí téńté orí Òkè Nébò ní ilẹ̀ Móábù. Ó ṣeé ṣe fún Mósè láti wò ré kọjá Odò Jọ́dánì láti orí òkè ọ̀hún kó sì rí ilẹ̀ Kénáánì dáradára yẹn. Jèhófà wí pé: ‘Èyí ni ilẹ̀ náà tí mo ti ṣèlérí láti fún àwọn ọmọ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Mo ti jẹ́ kó o rí i, ṣùgbọ́n mi ò ní jẹ́ kó o wọ inú rẹ̀.’

Orí Òkè Nébò níbẹ̀ ni Mósè kú sí. Ẹni ọgọ́fà [120] ọdún ni. Alágbára ṣì ni, ojú rẹ̀ sì ń ríran rekete. Inú àwọn èèyàn náà bà jẹ́ gidigidi wọ́n sì sunkún nítorí ikú Mósè. Ṣùgbọ́n inú wọn tún dùn pé àwọn ní Jóṣúà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wọn tuntun.