Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 45

Bí Wọ́n Ṣe La Odò Jọ́dánì Kọjá

Bí Wọ́n Ṣe La Odò Jọ́dánì Kọjá

WÒ Ó! Odò Jọ́dánì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì mà ń là kọjá yìí! Àmọ́ ibo lomi náà lọ? Dẹ́múdẹ́mú ni odò náà kún dẹ́nu ní ìṣẹ́jú mélòó kan ṣáájú ìgbà tí wọ́n ń kọjá yìí nítorí ọ̀pọ̀ òjò tó máa ń rọ̀ lákòókò yìí nínú ọdún. Àmọ́ a ò rí omi kankan mọ́! Orí ilẹ̀ gbígbẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn kọjá gan-an bí wọ́n ti ṣe nígbà tí wọ́n ń sọdá Òkun Pupa! Ibo ni gbogbo omi náà lọ? Jẹ́ ká wò ó.

Nígbà tí àkókò tó káwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Odò Jọ́dánì kọjá, ohun tí Jèhófà ní kí Jóṣúà sọ fún àwọn èèyàn náà nìyí: ‘Káwọn àlùfáà gbé àpótí májẹ̀mú kí wọ́n sì máa lọ níwájú. Tí wọ́n bá ti ki ẹsẹ bọ inú omi Odò Jọ́dánì báyìí, omi náà ò ní ṣàn mọ́.’

Làwọn àlùfáà bá gbé àpótí ẹ̀rí náà, wọ́n ń gbé e lọ níwájú àwọn èèyàn náà. Nígbà tí wọ́n dé etí Odò Jọ́dánì, àwọn àlùfáà náà ki ẹsẹ̀ wọn bọnú omi. Omi náà ń ṣàn tagbára-tagbára tẹ́lẹ̀. Àmọ́ bí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà ṣe kan omi náà báyìí, ṣe ni omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í dáwọ́ ṣíṣàn dúró! Iṣẹ́ ìyanu ni! Jèhófà ti dá omi náà dúró lápá òkè. Nítorí náà, kò pẹ́ tí kò fi sí omi mọ́ lójú odò náà!

Àwọn àlùfáà tó gbé àpótí ẹ̀rí náà, rìn lọ tààrà sí agbedeméjì ojú odò náà. Ṣó o rí wọn nínú àwòrán yìí? Bí wọ́n ti dúró síbẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn kọjá ojú Odò Jọ́dánì tó ti gbẹ!

Nígbà tí gbogbo wọn ti la odò náà kọjá tán, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé kó sọ fáwọn ọkùnrin méjìlá tó lágbára pé: ‘Ẹ lọ sí ibi tí àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí náà dúró sí lójú odò. Ẹ ṣa òkúta méjìlá níbẹ̀, kẹ́ ẹ sì tò wọ́n sí ibi tẹ́ ẹ máa dúró sí ní alẹ́ òní. Tó bá wá di ọjọ́ iwájú, táwọn ọmọ yín bá béèrè ohun táwọn òkúta wọ̀nyí dúró fún, kẹ́ ẹ wí fún wọn pé omi dẹ́kun ṣíṣàn nígbà tí àpótí ẹ̀rí Jèhófà la Jọ́dánì kọjá. Òkúta wọ̀nyí láá máa rán yín létí iṣẹ́ ìyanu yìí!’ Jóṣúà pẹ̀lú to òkúta méjìlá jọ síbi tí àwọn àlùfáà náà dúró sí láàárín ojú odò náà.

Níkẹyìn, Jóṣúà wí fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí ẹ̀rí náà pé: ‘Ẹ jáde kúrò nínú Jọ́dánì.’ Gẹ́rẹ́ tí wọ́n sì jáde ni odò náà ti tún padà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn.