Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 36

Ère Ọmọ Màlúù Oníwúrà

Ère Ọmọ Màlúù Oníwúrà

HÁÀ! háà! Kí làwọn èèyàn yìí ń ṣe yìí? Wọ́n ń gbàdúrà sí ère ọmọ màlúù! Kí ló ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀?

Nígbà tí Mósè kò tètè dé láti orí òkè, àwọn èèyàn náà wí pé: ‘Àwa ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe ọlọ́run kan tí yóò sìn wá jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí.’

Áárónì, ẹ̀gbọ́n Mósè sọ pé: ‘Kò burú. Ẹ bọ́ yẹrí oníwúrà etí yín, kẹ́ ẹ sì kó wọn wá fún mi.’ Nígbà táwọn èèyàn náà ṣe bẹ́ẹ̀, Áárónì yọ́ gbogbo yẹrí oníwúrà náà ó sì fi ṣe ère ọmọ màlúù. Àwọn èèyàn náà wá sọ pé: ‘Ọlọ́run wa tó mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì nìyí!’ Ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ àríyá ńlá tí wọ́n sì ń jọ́sìn ère ọmọ màlúù náà.

Nígbà tí Jèhófà rí èyí, inú bí i gidigidi. Nítorí náà, ó sọ fún Mósè pé: ‘Yára sọ̀ kalẹ̀ lọ. Ohun táwọn èèyàn yìí ń ṣe lọ́wọ́ yìí burú púpọ̀. Wọ́n ti gbàgbé òfin mi wọ́n sì ń jọ́sìn ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe.’

Mósè yára sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè náà. Nígbà tó sì sún mọ́ wọn, ohun tó rí nìyí. Àwọn èèyàn náà ń kọrin wọ́n sì ń jó yí ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe ká! Inú bí Mósè gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tó fi la àwọn wàláà òkúta méjì náà tí òfin mẹ́wàá wà nínú rẹ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ sí wẹ́wẹ́. Ìgbà náà ló wá mú ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe náà tó sì yọ́ ọ. Ó wá lọ̀ ọ́ lúúlúú.

Ohun tó burú gbáà làwọn èèyàn náà ṣe. Nítorí náà, Mósè sọ fún àwọn kan pé kí wọ́n mú idà wọn. Mósè wí pé: ‘Àwọn ẹni búburú tó sin ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe náà gbọ́dọ̀ kú.’ Nítorí náà, wọ́n fi idà pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn! Èyí kò ha fi hàn pé a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká rí i pé Jèhófà nìkan là ń sìn, ká má sì sin àwọn ọlọ́run èké?