Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 54

Ọkùnrin Tó Lágbára Jù Lọ

Ọkùnrin Tó Lágbára Jù Lọ

ǸJẸ́ o mọ orúkọ ọkùnrin tó lágbára jù lọ tó tíì gbé ayé rí? Onídàájọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sámúsìnì ni. Jèhófà ló fún Sámúsìnì ní agbára tó ní. Kí wọ́n tiẹ̀ tó bí Sámúsìnì pàápàá ni Jèhófà ti sọ fún ìyá rẹ̀ pé: ‘Láìpẹ́ wàá bí ọmọkùnrin kan. Òun ló máa jẹ́ aṣáájú láti gba Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filísínì.’

Èèyàn búburú làwọn ará Filísínì, Kénáánì ni wọ́n ń gbé. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ jagunjagun, wọ́n sì ń ṣe ìpalára gan-an fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ní ìgbà kan, tí Sámúsìnì ń lọ sí ibi tí àwọn ará Filísínì ń gbé, kìnnìún ńlá kan tó ń ké ramúramù jáde wá pàdé rẹ̀. Àmọ́ ọwọ́ lásán ni Sámúsìnì fi pa kìnnìún náà. Ó tún pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará Filísínì búburú náà.

Nígbà tó yá Sámúsìnì nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dèlílà. Àwọn olórí nínú àwọn ará Filísínì ṣèlérí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn yóò fún Dèlílà ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] owó fàdákà bó bá lè sọ ìdí tí Sámúsìnì fi lágbára tó bẹ́ẹ̀ fún àwọn. Dèlílà fẹ́ owó tó pọ̀ yẹn. Ìfẹ́ tòótọ́ kọ́ ló ní sí Sámúsìnì àti sáwọn èèyàn Sámúsìnì. Nítorí náà, ìgbà gbogbo ló ń béèrè lọ́wọ́ Sámúsìnì pé kó sọ ohun tó fún un lágbára tó bẹ́ẹ̀ fún òun.

Nígbà tó yá, Dèlílà ṣe é títí tí Sámúsìnì fi sọ àṣírí agbára rẹ̀ fún un. Sámúsìnì wí pé: ‘Wọn ò gé irun orí mi rí. Ìgbà tí wọ́n ti bí mi ni Ọlọ́run ti yàn mí láti jẹ́ Násírì, tó jẹ́ ìránṣẹ́ pàtàkì fún Ọlọ́run. Bí wọ́n bá gé irun orí mi, mi ò ní lágbára mọ́.’

Nígbà tí Dèlílà gbọ́ àṣírí yìí, ó jẹ́ kí Sámúsìnì sùn lórí itan rẹ̀. Ó wá pe ọkùnrin kan wọlé pé kó wá gé irun Sámúsìnì. Ìgbà tí Sámúsìnì jí, kò lágbára mọ́. Báwọn ará Filísínì ṣe wọlé tí wọ́n sì mú un ní ìgbèkùn nìyẹn. Wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì fi í ṣe ẹrú wọn.

Lọ́jọ́ kan àwọn ará Filísínì ń ṣe àjọyọ̀ ńlá kan láti jọ́sìn Dágónì òrìṣà wọn, wọ́n sì mú Sámúsìnì jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n láti fi í ṣe ẹlẹ́yà. Nígbà tó fi máa di àkókò yìí, irun Sámúsìnì tún ti gùn padà. Sámúsìnì wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin tó ń mú un rìn pé: ‘Jẹ́ kí n fọwọ́ kan àwọn òpó tó gbé ilé yìí ró.’ Ni Sámúsìnì bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun lágbára, ló bá di àwọn òpó náà mú. Ó kígbe ní ohùn rara pé: ‘Jẹ́ kí n kú pẹ̀lú àwọn ará Filísínì.’ Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àwọn ará Filísínì ló wà ní ibi àjọyọ̀ náà, nígbà tí Sámúsìnì sì fi ara ti àwọn òpó náà, ilé náà wó, ó sì pa gbogbo èèyàn búburú wọ̀nyẹn.