Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 71

Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè

ÀWÒRÁN Párádísè kan nìyí, irú èyí tó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run ti fi han Aísáyà wòlíì rẹ̀. Aísáyà gbé láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jónà kú.

Párádísè túmọ̀ sí “ọgbà” tàbí “ibi ìtura.” Ṣé kò rán ẹ létí ohun kan tá a ti rí tẹ́lẹ̀ nínú ìwé yìí? Ó jọ ọgbà ẹlẹ́wà tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún Ádámù àti Éfà lọ́pọ̀lọpọ̀, àbí kò jọ ọ́? Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ gbogbo ayé lè di Párádísè bí?

Jèhófà sọ fún Aísáyà wòlíì rẹ̀ pé kó kọ̀wé nípa Párádísè tuntun tó ń bọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó wí pé: ‘Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn á jùmọ̀ máa gbé pọ̀ lálàáfíà. Àwọn ọmọ màlúù àti ọmọ kìnnìún á máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ kéékèèké á máa ṣe ìtọ́jú wọn. Àní bí ọmọ ọwọ́ bá ń ṣeré nítòsí ejò olóró, kò ní pa á lára.’

Ọ̀pọ̀ èèyàn láá sọ pé: ‘Ìyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ láéláé. Kò sígbà tí kò sí ìṣòro ní ayé, kò sì sígbà tí ìṣòro máa tán láyé.’ Ṣùgbọ́n ronú nípa rẹ̀: Irú ilé wo ni Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà?

Ṣebí inú Párádísè ni Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà sí. Nítorí pé wọ́n ṣe àìgbọràn sí Ọlọ́run ni wọ́n fi pàdánù ilé wọn ẹlẹ́wà, tí wọ́n fi darúgbó tí wọ́n sì kú. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tó fẹ́ràn òun ní àwọn nǹkan tí Ádámù àti Éfà pàdánù rẹ̀ gan-an.

Nínú Párádísè tó ń bọ̀ kò sí ohun tó máa pani lára tàbí pani run. Àlàáfíà pípé yóò wà. Gbogbo èèyàn ló máa láyọ̀ tí wọ́n sì máa lágbára. Bí Ọlọ́run ti fẹ́ kó rí ní ìbẹ̀rẹ̀ gẹ́lẹ́ ló máa rí. Ṣùgbọ́n a máa rí i níwájú bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe èyí.