Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 60

Ábígẹ́lì àti Dáfídì

Ábígẹ́lì àti Dáfídì

ṢÉ O mọ arẹwà obìnrin tó ń bọ̀ wá pàdé Dáfídì yìí? Ábígẹ́lì lorúkọ rẹ̀. Olórí pípé obìnrin ni, òun ni kò sì jẹ́ kí Dáfídì ṣe ohun búburú kan. Àmọ́ ká tó kọ́ nípa ìyẹn, jẹ́ ká wo ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ná.

Lẹ́yìn tí Dáfídì ti sá kúrò lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó fara pa mọ́ sínú ihò kan. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àtàwọn ará ilé rẹ̀ tó kù lọ bá a níbẹ̀. Àpapọ̀ nǹkan bí irínwó [400] ọkùnrin ló lọ bá a, Dáfídì sì di aṣáájú wọn. Dáfídì wá tọ ọba Móábù lọ, ó sì wí pé: ‘Jọ̀ọ́, jẹ́ kí bàbá àti ìyá mi máa gbé lọ́dọ̀ rẹ títí tí màá fi rí ibi tọ́ràn mi máa yọrí sí.’ Nígbà tó yá, Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fara pa mọ́ sáàárín àwọn òkè.

Ẹ̀yìn èyí ni Dáfídì pàdé Ábígẹ́lì. Nábálì ọkọ rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀ tó ní ilẹ̀ púpọ̀. Ó ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àgùntàn àti ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ewúrẹ́. Aláròró èèyàn ni Nábálì. Àmọ́ Ábígẹ́lì ìyàwó rẹ̀ jẹ́ arẹwà obìnrin. Ó tún mọ bá a ti í ṣe ohun tó tọ́. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó kó ìdílé rẹ̀ yọ nínú ewu. Jẹ́ ká wo bó ṣe se é.

Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ ti ṣe Nábálì lóore. Wọ́n bá a dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan, Dáfídì rán díẹ̀ lára àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Nábálì. Àwọn tí Dáfídì rán dé ọ̀dọ̀ Nábálì lákòókò tí òun àtàwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ ń rẹ́ irun àgùntàn. Ọjọ́ àsè ni, Nábálì sì ní ọ̀pọ̀ nǹkan téèyàn lè jẹ. Nítorí náà, àwọn èèyàn Dáfídì wí pé: ‘A ti ṣe ọ lóore rí. A ò jí ọ̀kankan nínú àwọn àgùntàn rẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la bá ọ bójú tó wọn. Jọ̀ọ́ wá fún wa lóúnjẹ díẹ̀ báyìí.’

Nábálì wí pé: ‘Láéláé, mi ò lè fún àwọn èèyàn bíi tiyín ni oúnjẹ mi.’ Ó sọ̀rọ̀ bí aláìláàánú, ó sì sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa Dáfídì. Nígbà táwọn èèyàn náà padà dé ọ̀dọ̀ Dáfídì tí wọ́n sì sọ fún un, inú bí Dáfídì gidigidi. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ mú idà yín!’ Wọ́n sì kọrí sọ́nà láti lọ pa Nábálì àtàwọn èèyàn rẹ̀.

Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin Nábálì tó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ burúkú tí Nábálì sọ ló sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Ábígẹ́lì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ábígẹ́lì wá oúnjẹ. Ó gbé e ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì mú kọ́rí sọ́nà. Nígbà tó pàdé Dáfídì, ó bọ́ sílẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ó sì tẹrí ba ó wí pé: ‘Olúwa mi, ẹ jọ̀ọ́, ẹ má ka ọ̀rọ̀ ọkọ̀ mi Nábálì sí. Aláìmòye kan ni, ó sì máa ń hùwà aláìmọ̀kan. Ẹ̀bùn tí mo kó wá nìyí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbà á, kẹ́ ẹ sì dárí ohun tó ṣẹlẹ̀ jì wá.’

Dáfídì dáhùn pé: ‘Orí ẹ pé, ìwọ obìnrin yìí. Ìwọ lo ò jẹ́ kí n pa Nábálì láti gbẹ̀san ìwà búburú rẹ̀ padà. Máa wá lọ sí ilé ní àlàáfíà.’ Lẹ́yìn ìyẹn, Nábálì kú, Ábígẹ́lì di ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Dáfídì.