Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 58

Dáfídì àti Gòláyátì

Dáfídì àti Gòláyátì

ÀWỌN Filísínì tún wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà. Àwọn ẹ̀gbọ́n Dáfídì mẹ́ta àgbà ti wà lára àwọn ọmọ ogun Sọ́ọ̀lù. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan, Jésè sọ fún Dáfídì pé: ‘Mú ọkà àti àkàrà díẹ̀ lọ fáwọn ẹ̀gbọ́n rẹ. Kó o béèrè àlàáfíà wọn.’

Nígbà tí Dáfídì dé ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sáré lọ síbi ojú ogun láti lọ wá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àkókò yẹn ni Gòláyátì òmìrán Filísínì jáde wá láti fàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́yà. Bó ṣe ń ṣe nìyẹn láràárọ̀ àti lálaalẹ́ fún ogójì ọjọ́. Ó kígbe pé: ‘Ẹ yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin yín pé kó wá bá mi jà. Bó bá borí, tó sì pa mí, a máa di ẹrú yín. Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣẹ́gun rẹ̀ tí mo sì pa á, ẹ máa di ẹrú wa. Tẹ́ ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ kẹ́ ẹ yan ẹnì kan pé kó wá bá mi jà.’

Dáfídì béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun kan pé: ‘Kí lẹni tó bá pa Filísínì yìí tó sì gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ ìtìjú máa gbà?’

Ọmọ ogun náà dáhùn pé: ‘Sọ́ọ̀lù á fún ẹni náà ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Á sì tún fún onítọ̀hún ní ọmọbìnrin rẹ̀ láti fi ṣe ìyàwó.’

Ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì ni ẹ̀rù Gòláyátì ń bà nítorí pé ó ti tóbi gan-an. Ó ga ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án (ìyẹn nǹkan bíi mítà mẹ́ta) lọ, ó sì tún ní ọmọ ogun mìíràn tó ń gbé apata fún un.

Àwọn ọmọ ogun kan lọ, wọ́n sì sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé Dáfídì sọ pé òun á bá Gòláyátì jà. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: ‘O ò ní lè bá Filísínì yìí jà o. Ọmọdé ni ọ́, jagunjagun sì ni òun ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.’ Dáfídì dáhùn pé: ‘Mo pa béárì àti kìnnìún tó fẹ́ gbé àgùntàn bàbá mi lọ. Filísínì yìí á sì dà bí ọ̀kan nínú wọn. Jèhófà á ràn mí lọ́wọ́.’ Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Lọ, kí Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ.’

Dáfídì lọ sí etí odò kan, ó sì ṣa òkúta wẹ́wẹ́ márùn-ún tó jọ̀lọ̀, ó sì kó wọn sínú àpò rẹ̀. Ó wá mú kànnàkànnà rẹ̀ ó sì lọ kojú òmìrán náà. Nígbà tí Gòláyátì rí i, ó yà á lẹ́nu. Èrò rẹ̀ ni pé kò lè ṣòro láti pa Dáfídì.

Gòláyátì lérí pé: ‘Ìwọ máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, màá fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ àti ẹranko jẹ.’ Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé: ‘Ìwọ́ kó ọ̀kọ̀, idà àti apata wá sọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ wá bọ́ ẹ ní orúkọ Jèhófà. Jèhófà á fi ẹ́ lé mi lọ́wọ́ lónìí yìí, màá sì pa ẹ́.’

Bó ṣe sọ báyìí tán, Dáfídì sáré sọ́dọ̀ Gòláyátì. Ó mú òkúta kan láti inú àpò rẹ̀, ó fi í sínú kànnàkànnà rẹ̀, ó sì fi gbogbo agbára rẹ̀ fà á. Òkúta náà wọ agbárí Gòláyátì lọ ní tààràtà, ó ṣubú lulẹ̀ ó sì kú! Nígbà táwọn Filísínì rí i pé olórí ogun àwọn ti ṣubú, gbogbo wọ́n yíjú padà wọ́n feré gé e. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbá tẹ̀ lé wọn, bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun nìyẹn o.