Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 62

Wàhálà Nínú Ilé Dáfídì

Wàhálà Nínú Ilé Dáfídì

LẸ́YÌN tí Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní Jerúsálẹ́mù, Jèhófà mú káwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. Jèhófà ti ṣèlérí láti fi ilẹ̀ Kénáánì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wàyí o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, gbogbo ilẹ̀ tó ṣèlérí fún wọn ti di tiwọn níkẹyìn.

Alákòóso rere ni Dáfídì. Ó fẹ́ràn Jèhófà. Nítorí náà, ọ̀kan nínú àwọn ohun tó kọ́kọ́ ṣe lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù ni pé ó gbé àpótí ẹ̀rí Jèhófà wá sí ibẹ̀. Ó sì fẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan tó máa gbé e sí.

Nígbà tí Dáfídì dàgbà, ó ṣe àṣìṣe burúkú kan. Dáfídì mọ̀ pé kò tọ́ láti mú ohun tó jẹ́ ti ẹlòmíì. Ṣùgbọ́n ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tó wà ní orí òrùlé ààfin rẹ̀, ó wo ìsàlẹ̀ ó sì rí arẹwà obìnrin kan. Orúkọ rẹ̀ ni Bátí-ṣébà, Ùráyà tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun Dáfídì.

Ojú Dáfídì wọ Bátí-ṣébà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi pàṣẹ pé kí wọ́n mú un wá sí ààfin òun. Ọkọ obìnrin náà wà ní ibi tó ti ń jagun. Lẹ́nu kan ṣá, Dáfídì bá obìnrin náà dà pọ̀, ó sì wá gbọ́ lẹ́yìn náà pé obìnrin náà lóyún. Ọkàn Dáfídì ò balẹ̀ mọ́ ó sì ránṣẹ́ sí Jóábù olórí ogun pé kó jẹ́ kí Ùráyà wà ní iwájú ogun níbi tí wọ́n á ti pa á. Nígbà tí Ùráyà kú, Dáfídì gbé Bátí-ṣébà ní ìyàwó.

Jèhófà bínú gidigidi sí Dáfídì. Nítorí náà, ó rán Nátánì ìránṣẹ́ rẹ̀ sí i pé kó sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un. Nátánì lo rí tó ń bá Dáfídì sọ̀rọ̀ yẹn. Dáfídì kábàámọ̀ ohun tó ṣe, nítorí náà, Jèhófà kò fi ikú pa á. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé: ‘Nítorí pé o ṣe àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí, wàhálà púpọ̀ máa wà nínú ilé rẹ.’ Ojú Dáfídì mà rí ọ̀pọ̀ wàhálà o!

Lákọ̀ọ́kọ́, ọmọ tí Bátí-ṣébà bí kú. Lẹ́yìn náà, Ámínónì àkọ́bí Dáfídì ọkùnrin fi ipá bá Támárì àbúrò rẹ̀ obìnrin lò pọ̀. Ìyẹn bí Ábúsálómù ọmọkùnrin Dáfídì nínú gan-an débi tó fi pa Ámínónì. Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gba ti Ábúsálómù, ó sì sọ ara rẹ̀ di ọba. Níkẹyìn, Dáfídì borí nínú ogun tó bá Ábúsálómù jà, Ábúsálómù kú. O ò rí i pé wàhálà tó dé bá Dáfídì pọ̀ gan-an ni.

Láàárín gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Bátí-ṣébà bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sólómọ́nì. Nígbà tí Dáfídì di arúgbó tí ara rẹ̀ ò sì yá mọ́, Ádóníjà ọmọ rẹ̀ ọkùnrin gbìyànjú láti sọ ara rẹ̀ di ọba. Ni Dáfídì bá ní kí àlùfáà kan tó ń jẹ́ Sádókù da òróró sórí Sólómọ́nì láti fi hàn pé Sólómọ́nì ló máa di ọba. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Dáfídì kú ní ẹni àádọ́rin [70] ọdún. Ogójì [40] ọdún ló fi ṣàkóso, ṣùgbọ́n Sólómọ́nì ni ọba Ísírẹ́lì nísinsìnyí.