Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 61

Wọ́n Fi Dáfídì Jọba

Wọ́n Fi Dáfídì Jọba

SỌ́Ọ̀LÙ tún gbìyànjú láti mú Dáfídì. Ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó mọ ogun jà jù lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri. Nígbà tí Dáfídì gbọ́, ó rán àwọn amí jáde láti mọ ibi tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ní òru ọjọ́ yẹn. Dáfídì wá béèrè lọ́wọ́ méjì nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: ‘Ta ló máa bá mi lọ sí ibùdó Sọ́ọ̀lù nínú yín?’

Ábíṣáì dáhùn pé: ‘Màá lọ.’ Ábíṣáì ni ọmọ Seruáyà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dáfídì obìnrin. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn rẹ̀ ń sùn, Dáfídì àti Ábíṣáì rọra yọ́ wọnú àgọ́ wọn. Wọ́n mú ọ̀kọ̀ Sọ́ọ̀lù àti ṣágo omi rẹ̀, èyí tó wà lẹ́bàá ìgbèrí Sọ́ọ̀lù gan-an. Kò sẹ́ni tó rí wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó gbúròó wọn torí gbogbo àwọn èèyàn Sọ́ọ̀lù ló ti sùn lọ fọnfọn.

Wo Dáfídì àti Ábíṣáì nísinsìnyí. Wọ́n ti sá kúrò níbẹ̀, wọ́n wà lórí òkè kan níbi tọ́wọ́ ò ti lè tẹ̀ wọ́n. Dáfídì ké sí olórí ogun Ísírẹ́lì látorí òkè pé: ‘Ábínérì, kí ló dé tó ò fi dáàbò bo olúwa rẹ, ọba? Wò ó! Ibo ni ọ̀kọ̀ àti ṣágo omi rẹ̀ wà?’

Sọ́ọ̀lù ta jí. Ó gbọ́ ohùn Dáfídì, ó sì béèrè pé: ‘Àbí ìwọ kọ́ yẹn ni, Dáfídì?’ Ṣó o rí Sọ́ọ̀lù àti Ábínérì nísàlẹ̀?

Dáfídì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: ‘Èmi ni, olúwa mi ọba.’ Dáfídì sì béèrè pé: ‘Kí ló dé tẹ́ ẹ fi fẹ́ mú mi? Ohun búburú wo ni mo ṣe? Ọ̀kọ̀ yín ló wà lọ́wọ́ mi yìí, ọba. Ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn èèyàn yín wá gbà á.’

Sọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Ohun tí mo ṣe ò dáa. Mo ti hùwà bí òmùgọ̀.’ Bí Dáfídì ṣe bá tiẹ̀ lọ nìyẹn, Sọ́ọ̀lù sì padà sí ilé. Ṣùgbọ́n Dáfídì sọ ọ́ nínú ọkàn rẹ̀ pé: ‘Lọ́jọ́ kan, Sọ́ọ̀lù á pa mí. Àfi kí n yáa sá lọ sí ilẹ̀ àwọn Filísínì.’ Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Dáfídì dọ́gbọ́n tan àwọn Filísínì jẹ, ó mú kí wọ́n gbà pé tiwọn lòun ń ṣe báyìí.

Nígbà tó yá, àwọn Filísínì gòkè lọ láti bá Ísírẹ́lì jagun. Nínú ogun yẹn, wọ́n pa Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì. Ó dun Dáfídì gan-an ni, ó sì kọ orin arò kan, nínú èyí tó ti wí pé: ‘Inú mi bà jẹ́ nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi. O mà ṣọ̀wọ́n fún mi púpọ̀ o!’

Lẹ́yìn èyí, Dáfídì padà sí Ísírẹ́lì sí ìlú Hébúrónì. Ogun bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn tó yan Iṣibóṣẹ́tì ọmọ Sọ́ọ̀lù láti jọba àtàwọn èèyàn mìíràn tó fẹ́ kí Dáfídì jọba. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn Dáfídì borí nígbẹ̀yìn. Dáfídì jẹ́ ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún nígbà tí wọ́n fi í jọba. Ọdún méje àtààbọ̀ ló fi jọba ní Hébúrónì. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọ tó bí níbẹ̀ lorúkọ wọn ń jẹ́ Ámínónì, Ábúsálómù àti Ádóníjà.

Nígbà tí àkókò tó, Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ gòkè lọ láti gba ìlú dáradára kan tó ń jẹ́ Jerúsálẹ́mù. Jóábù, òmíràn nínú àwọn ọmọ Seruáyà tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Dáfídì obìnrin, ló ṣáájú nínú ìjà yẹn. Nítorí náà, Dáfídì dá Jóábù lọ́lá nípa sísọ ọ́ di olórí ogun rẹ̀. Dáfídì wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ìlú Jerúsálẹ́mù.