Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 57

Ọlọ́run Yan Dáfídì

Ọlọ́run Yan Dáfídì

SÉ O rí ohun tó ṣẹlẹ̀ níbí yìí? Ọmọkùnrin tó ò ń wò yìí ti gba ọ̀dọ́ àgùntàn ọwọ́ rẹ̀ yẹn lẹ́nu béárì. Béárì gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà lọ ó fẹ́ pa á jẹ. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin yìí sá tẹ̀ lé e, ó sì gba ọ̀dọ́ àgùntàn náà lẹ́nu béárì. Ìgbà tí béárì kọjú ìjà sí ọmọkùnrin yìí, ó gbá béárì náà mú ó sì lù ú pa! Àkókò kan tún wà tí ọmọkùnrin yìí gba ọ̀kan nínú àwọn àgùntàn rẹ̀ lẹ́nu kìnnìún. O ò rí i pé onígboyà ọmọ ni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ o mọ ọmọ yẹn?

Dáfídì nìyẹn nígbà tó wà lọ́mọdé. Ó ń gbé ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Óbédì, ọmọ tí Rúùtù àti Bóásì bí, ni bàbá bàbá rẹ̀. Ṣó o rántí Rúùtù àti Bóásì? Jésè ni bàbá Dáfídì. Dáfídì máa ń tọ́jú àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí Jèhófà yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba ni wọ́n bí Dáfídì.

Lọ́jọ́ kan, Jèhófà wí fún Sámúẹ́lì pé: ‘Mú àkànṣe òróró kó o sì lọ sí ilé Jésè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Mo ti yan ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ láti di ọba.’ Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Élíábù tó jẹ́ àkọ́bí nínú ọmọ Jésè, ó sọ ọ́ sínú pé: ‘Dájúdájú, ẹni tí Jèhófà yàn nìyí.’ Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún un pé: ‘Má wo bó ṣe ga àti bó ṣe rẹwà tó. Òun kọ́ ni mo yàn pé kó jẹ ọba.’

Nítorí náà Jésè pe ọmọ rẹ̀ Ábínádábù ó sì mú un lọ bá Sámúẹ́lì. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí pé: ‘Rárá, ẹni yìí kọ́ ni Jèhófà yàn.’ Lẹ́yìn náà, Jésè mú Ṣámáhì ọmọ rẹ̀ wá. Sámúẹ́lì wí pé: ‘Rárá, Jèhófà ò yan eléyìí pẹ̀lú.’ Jésè mú méje nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì, ṣùgbọ́n Jèhófà kò yan èyíkéyìí nínú wọn. Sámúẹ́lì béèrè pé: ‘Ṣé gbogbo àwọn ọmọkùnrin tó o bí rèé?’

Jésè wí pé: ‘Èyí tó kéré jù ṣì wà. Ṣùgbọ́n ibi tó ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn nínú pápá ló wà.’ Nígbà tó mú Dáfídì wá, Sámúẹ́lì rí i pé arẹwà ọmọkùnrin ni. Jèhófà wí pé: ‘Òun nìyí. Da òróró sí i lórí.’ Sámúẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ọjọ́ ń bọ̀ tí Dáfídì á di ọba Ísírẹ́lì.