Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 65

Ìjọba Náà Pín sí Méjì

Ìjọba Náà Pín sí Méjì

ǸJẸ́ o mọ ohun tó fà á tí ọkùnrin yìí fi ń fa aṣọ rẹ̀ ya sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ? Jèhófà ló ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin yìí ni Áhíjà, wòlíì Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tá à ń pè ní wòlíì? Wòlíì ni ẹni tí Ọlọ́run máa ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún kó tó di pé ó ṣẹlẹ̀.

Jèróbóámù ni Áhíjà ń bá sọ̀rọ̀ yìí. Jèróbóámù ni ọkùnrin kan tí Sólómọ́nì ní kó máa bójú tó díẹ̀ lára iṣẹ́ ilé tó ń kọ́. Nígbà tí Áhíjà pàdé Jèróbóámù lójú ọ̀nà yìí, Áhíjà ṣe ohun àjèjì kan. Ó mú ẹ̀wù tuntun tó wọ̀ sọ́rùn ó sì ya á sí ọ̀nà méjìlá. Ó sọ fún Jèróbóámù pé: ‘Mú mẹ́wàá níbẹ̀.’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Áhíjà fi fún Jèróbóámù ní mẹ́wàá?

Áhíjà ṣàlàyé pé Jèhófà máa gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Sólómọ́nì. Ó sọ pé Jèhófà á fún Jèróbóámù ní ẹ̀yà mẹ́wàá. Èyí túmọ̀ sí pé ẹ̀yà méjì péré ló máa kù fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì láti máa ṣàkóso lé lórí.

Nígbà tí Sólómọ́nì gbọ́ ohun tí Áhíjà sọ fún Jèróbóámù, inú bí i gan-an. Ó gbìyànjú láti pa Jèróbóámù. Ṣùgbọ́n Jèróbóámù sá lọ sí Íjíbítì. Nígbà tó ṣe díẹ̀, Sólómọ́nì kú. Ó jọba fún ogójì [40] ọdún, ṣùgbọ́n Rèhóbóámù ọmọ rẹ̀ ni wọ́n fi jọba nísinsìnyí. Íjíbítì ni Jèróbóámù wà tó ti gbọ́ pé Sólómọ́nì ti kú, nítorí náà ó padà wá sí Ísírẹ́lì.

Rèhóbóámù kì í ṣe ọba dáadáa. Ó tiẹ̀ tún rorò sí àwọn èèyàn náà ju Sólómọ́nì bàbá rẹ̀ lọ. Jèróbóámù àtàwọn èèyàn pàtàkì-pàtàkì kan tọ Rèhóbóámù Ọba lọ, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó máa ṣe dáadáa sáwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n Rèhóbóámù ò gbọ́. Àní, ṣe ló tiẹ̀ tún burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Torí náà, àwọn èèyàn fi Jèróbóámù jọba lórí ẹ̀yà mẹ́wàá, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà méjì, ìyẹn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì àti ẹ̀yà Júdà ṣì gba Rèhóbóámù gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.

Jèróbóámù kò fẹ́ káwọn èèyàn òun máa lọ sí Jerúsálẹ́mù láti jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, ó fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù méjì, ó sì mú kí àwọn èèyàn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá yẹn máa jọ́sìn wọn. Kò pẹ́, kò jìnnà tí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá fi kún ilẹ̀ náà.

Ìjọba ẹ̀yà méjì pẹ̀lú ò ṣàìní wàhálà tiẹ̀. Láìtí ì pé ọdún márùn-ún lẹ́yìn tí Rèhóbóámù di ọba, ọba Íjíbítì wá bá Jerúsálẹ́mù jà. Ó sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣúra lọ látinú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Nítorí náà, àkókò díẹ̀ péré ni tẹ́ńpìlì náà fi wà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nígbà tí wọ́n kọ́ ọ.