ÌTÀN 70
Jónà àti Ẹja Ńlá Náà
WO ỌKÙNRIN tó wà nínú omi yìí. Inú ìṣòro ńláǹlà ló wà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ẹja yẹn fẹ́ gbé e mì! Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ọkùnrin yìí jẹ́ bí? Jónà ni orúkọ rẹ̀. Jẹ́ ká wo bó ṣe bọ́ sínú wàhálà ńlá yìí.
Wòlíì Jèhófà ni Jónà. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ikú wòlíì Èlíṣà tí Jèhófà fi sọ fún Jónà pé: ‘Lọ sí ìlú ńlá Nínéfè. Ìwà búburú àwọn èèyàn ibẹ̀ ti pọ̀ jù, mo sì fẹ́ kó o bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.’
Ṣùgbọ́n Jónà kò fẹ́ lọ. Nítorí náà, ó wọ ọkọ̀ kan tó ń lọ sí ìbi tó jẹ́ òdìkejì Nínéfè. Inú Jèhófà kò dùn sí Jónà fún sísá tó ń sá lọ. Nítorí náà, Ó mú kí ìjì líle kan jà. Ìjì yẹn le tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ wọn fi fẹ́ máa rì. Ẹ̀rù ba àwọn atukọ̀ náà gan-an, wọ́n sì kígbe sí àwọn ọlọ́run wọn fún ìrànlọ́wọ́.
Níkẹyìn, Jónà sọ fún wọn pé: ‘Jèhófà ni èmi ń sìn, Ọlọ́run tó dá ọ̀run òun ayé. Èmi sì ń sá fún ṣíṣe ohun tí Jèhófà sọ fún mi pé kí n ṣe.’ Nítorí náà, àwọn atukọ̀ béèrè pé: ‘Kí ni ká ṣe sí ọ láti dá ìjì yìí dúró?’
Jónà wí pé: ‘Ẹ jù mí sínú òkun, òkun yóò sì padà pa rọ́rọ́.’ Àwọn atukọ̀ yẹn ò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìjì yẹn ti túbọ̀ ń pọ̀ sí i, nígbà tó yá, wọ́n ju Jónà sínú òkun. Kíá ni ìjì yẹn dáwọ́ dúró tí òkun sì pa rọ́rọ́.
Bí Jónà ti ń rì lọ sí ìsàlẹ̀ òkun, ẹja ńlá yìí gbé e mì. Ṣùgbọ́n kò kú. Fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta ló fi wà nínú ikùn ẹja yẹn. Jónà kábàámọ̀ gan-an pé òun ò ṣe ìgbọràn sí Jèhófà pé kí òun lọ sí Nínéfè. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe?
Jónà gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. Ìgbà náà ni Jèhófà mú kí ẹja yẹn pọ Jónà sórí ìyàngbẹ ilẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Jónà lọ sí Nínéfè. Ǹjẹ́ ìtàn yìí ò kọ́ wa pó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣe ohun tí Jèhófà bá sọ?
Ìwé Jónà nínú Bíbélì.