Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 73

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

ỌMỌ ọdún mẹ́jọ péré ni Jòsáyà nígbà tó di ọba ẹ̀yà méjì Ísírẹ́lì. Ọjọ́ orí yìí ti kéré jù fún èèyàn láti di ọba. Nítorí náà, àwọn àgbàlagbà kan kọ́kọ́ ràn án lọ́wọ́ láti ṣàkóso lórí orílẹ̀-èdè yẹn.

Nígbà tí Jòsáyà ti di ọba fún ọdún méje, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà. Ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọba rere bí Dáfídì, Jèhóṣáfátì àti Hesekáyà. Ó sì ṣe, nígbà tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, Jòsáyà ṣe ohun kan tó gba ìgboyà.

Ó ti pẹ́ tí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti burú gan-an. Wọ́n ń sin àwọn ọlọ́run èké. Wọ́n ń tẹrí ba fún àwọn òrìṣà. Nítorí náà, Jòsáyà jáde lọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìjọsìn èké kúrò ní ilẹ̀ náà. Iṣẹ́ ńláǹlà ni iṣẹ́ yìí nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sin ọlọ́run èké. Jòsáyà àti àwọn èèyàn rẹ̀ lo rí tí wọ́n ń wó àwọn ère lulẹ̀ yẹn nínú àwòrán yìí.

Nígbà tó yá, Jòsáyà gbé iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe lé àwọn èèyàn mẹ́ta kan lọ́wọ́. Wọ́n gba owó jọ lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì kó owó yẹn lé àwọn ẹni tí Jòsáyà yàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi san owó iṣẹ́ tí wọ́n ní láti ṣe. Nígbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì yẹn ṣe, Hilikáyà, àlùfáà àgbà rí ohun pàtàkì kan níbẹ̀. Ohun tó rí náà ni ìwé òfin gan-an tí Jèhófà ní kí Mósè kọ sílẹ̀ tipẹ́ sẹ́yìn. Ó ti sọ nù láti ọdún gbọ́n-han.

Wọ́n mú ìwé yẹn tọ Jòsáyà lọ, Jòsáyà sì ní kí wọ́n kà á fún òun. Bó ti ń fetí sílẹ̀, Jòsáyà rí i pé àwọn èèyàn ò pa òfin Jèhófà mọ́. Inú rẹ̀ bà jẹ́ gidigidi nítorí èyí, torí náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya gẹ́gẹ́ bó o ti rí i tó ń ṣe nínú àwòrán yìí. Ó wí pé: ‘Jèhófà ti bínú sí wa, nítorí pé àwọn bàbá wa kò pa òfin tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí mọ́.’

Jòsáyà pàṣẹ fún Hilikáyà àlùfáà àgbà pé kó wádìí ohun tí Jèhófà máa ṣe fún wọn. Hilikáyà tọ Húlídà tó jẹ́ wòlíì obìnrin lọ, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ó sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un, pé kó lọ sọ fún Jòsáyà pé: ‘Jerúsálẹ́mù àti gbogbo èèyàn inú rẹ̀ máa jẹ ìyà ohun tí wọ́n ṣe nítorí pé wọ́n ti jọ́sìn ọlọ́run èké, wọ́n sì ti fi ìwà búburú kún ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé ìwọ, Jòsáyà, ti ṣe ohun tó dára, ó di ẹ̀yìn ikú rẹ kí ìjìyà yìí tó dé.’