Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 74

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

Ọba Rere Tó Jẹ Kẹ́yìn ní Ísírẹ́lì

WO BÍ àwọn èèyàn ṣe ń fi ọ̀dọ́mọkùnrin yìí rẹ́rìn-ín. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà jẹ́? Jeremáyà ni orúkọ rẹ̀. Wòlíì pàtàkì ni fún Ọlọ́run.

Kété tí Jòsáyà Ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn òrìṣà ilẹ̀ náà run ni Jèhófà ti sọ fún Jeremáyà pé kó wá di wòlíì Òun. Àmọ́ ṣá, Jeremáyà rò pé òun kéré jù láti jẹ́ wòlíì. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún un pé Òun máa ràn án lọ́wọ́.

Jeremáyà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ohun búburú tí wọ́n ń ṣe. Ó wí pé: ‘Ọlọ́run èké ni òrìṣà tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn.’ Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ láti máa sin àwọn òrìṣà dípò kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́. Nígbà tí Jeremáyà sọ fún àwọn èèyàn yẹn pé Ọlọ́run máa jẹ wọ́n níyà torí ìwà búburú wọn, wọ́n wulẹ̀ ń fi í rẹ́rìn-ín ni.

Ọdún ń gorí ọdún. Jòsáyà kú, oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà ni ọmọ rẹ̀ Jèhóákímù di ọba. Jeremáyà ò yéé sọ fún àwọn èèyàn náà pé: ‘Wọ́n máa pa Jerúsálẹ́mù run bẹ́ ò bá yí ọ̀nà búburú yín padà.’ Àwọn àlùfáà gbá Jeremáyà mú, wọ́n ké ní ohùn rara pé: ‘O ní láti kú fún sísọ àwọn nǹkan wọ̀nyí.’ Wọ́n wá sọ fún àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì pé: ‘Jeremáyà ní láti kú, nítorí pé ó sọ̀rọ̀ lòdì sí ìlú wa.’

Kí ni Jeremáyà á wá ṣe nísinsìnyí o? Ẹ̀rù ò bà á rárá! Ó sọ fún gbogbo wọn pé: ‘Jèhófà ló rán mi láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún yín. Bẹ́ ò bá yí ọ̀nà búburú yín padà, Jèhófà máa pa Jerúsálẹ́mù run. Kẹ́ ẹ tún mọ èyí dájú pé: Bẹ́ ẹ bá pa mi, ẹni tí kò ṣe búburú kankan lẹ pa.’

Àwọn ọmọ aládé fi Jeremáyà sílẹ̀, wọn ò pa á, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò yí ọ̀nà búburú wọn padà. Nígbà tó yá, Nebukadinésárì ọba Bábílónì wá, ó sì bá Jerúsálẹ́mù jà. Níkẹyìn, Nebukadinésárì sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú rẹ̀. Ó kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú wọn lọ sí Bábílónì. Báwo ló ṣe máa rí ná bí àwọn àjèjì bá wá, kí wọ́n sì mú ọ kúrò ní ilé rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì!