Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 56

Sọ́ọ̀lù—Ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì

Sọ́ọ̀lù—Ọba Àkọ́kọ́ Ní Ísírẹ́lì

WO SÁMÚẸ́LÌ bó ti ń da òróró sórí ọkùnrin yìí. Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyí láti fi hàn pé wọ́n ti yan ẹnì kan ní ọba. Jèhófà ló ní kí Sámúẹ́lì da òróró sórí Sọ́ọ̀lù. Òróró olóòórùn dídùn kan báyìí tó yàtọ̀ ni òróró ọ̀hún.

Sọ́ọ̀lù ò ka ara rẹ̀ sẹ́ni tó lè jọba. Ó sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì tó kéré jù lọ ní Ísírẹ́lì ni mo ti wá. Kí ló dé tó o fi sọ pé èmi ni màá jọba?’ Jèhófà fẹ́ràn Sọ́ọ̀lù nítorí pé kò ka ara rẹ̀ sẹ́ni ńlá tàbí ẹni pàtàkì. Ìdí rẹ̀ nìyí tó fi yàn án láti jẹ́ ọba.

Àmọ́ Sọ́ọ̀lù kì í ṣe èèyàn yẹpẹrẹ o. Ilé olówó ló ti wá, ó sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin tó síngbọnlẹ̀. Ó fi nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà kan ga ju gbogbo àwọn tó kù ní Ísírẹ́lì lọ! Sárésáré ni Sọ́ọ̀lù, ó sì jẹ́ ọkùnrin tó lágbára gan-an. Inú àwọn èèyàn náà dùn pé Jèhófà yan Sọ́ọ̀lù láti jẹ ọba. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: ‘Kí ọba pẹ́!’

Agbára àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì kò fìgbà kan dín kù. Wọ́n ṣì ń yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nu gan-an ni. Kété lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di ọba, àwọn ará Ámónì wá láti bá wọn jà. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù kó ẹgbẹ́ ogun ńlá jọ, ó sì ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì. Èyí mú kí inú àwọn èèyàn náà dùn pé Sọ́ọ̀lù di ọba.

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Sọ́ọ̀lù ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun láti ṣẹ́gun ọ̀tá wọn. Sọ́ọ̀lù tún ní akíkanjú ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jónátánì. Jónátánì sì ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti borí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun. Àwọn Filísínì ni ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó burú jù lọ. Lọ́jọ́ kan ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Filísínì wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.

Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó dúró di ìgbà tí òun bá tó wá rú ẹbọ sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò tètè dé. Ẹ̀rù ba Sọ́ọ̀lù pé àwọn ará Filísínì lè dédé bẹ̀rẹ̀ ogun náà, ló bá kúkú fúnra rẹ̀ rú ẹbọ. Ìgbà tí Sámúẹ́lì dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé àìgbọràn ló ṣe. Ó ni: ‘Jèhófà á yan ẹlòmíì láti jẹ́ ọba lórí Ísírẹ́lì.’

Lẹ́yìn èyí, Sọ́ọ̀lù tún ṣàìgbọràn. Nítorí náà, Sámúẹ́lì sọ fún un pé: ‘Kéèyàn ṣègbọràn sí Jèhófà sàn ju kéèyàn fi àgùntàn rọ̀gbọ̀dọ̀ rúbọ sí Jèhófà lọ. Nítorí tó o ṣàìgbọràn sí Jèhófà, Jèhófà ò ní gbà kó o máa jọba lọ lórí Ísírẹ́lì.’

A lè rí ẹ̀kọ́ ńlá kọ́ nínú èyí. Ó fi hàn wá pé ó ṣe pàtàkì púpọ̀ pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo. Bákan náà, ó tún fi hàn wá pé bíi ti Sọ́ọ̀lù, ẹni rere kan lè yí padà kó sì di èèyàn búburú. Àwa ò ní í fẹ́ di èèyàn búburú láé, àbí?