Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 59

Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ

Ìdí Tí Dáfídì Fi Gbọ́dọ̀ Sá Lọ

LẸ́YÌN tí Dáfídì ti pa Gòláyátì, Ábínérì olórí ogun Ísírẹ́lì mú un lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù. Inú Sọ́ọ̀lù dùn gan-an sí Dáfídì. Ó sọ ọ́ di ọ̀kan nínú olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ó sì jẹ́ kó wá máa gbé ní ilé ọba.

Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun ti padà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ bá àwọn Filísínì jà, àwọn obìnrin ń kọrin pé: ‘Sọ́ọ̀lù pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ṣùgbọ́n Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún.’ Ìyẹn mú kí Sọ́ọ̀lù jowú, nítorí pé wọ́n yin Dáfídì ju òun lọ. Ṣùgbọ́n Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù ò jowú. Ó nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, Dáfídì pẹ̀lú sì nífẹ̀ẹ́ Jónátánì. Nítorí náà, àwọn méjèèjì ṣèlérí pé àwọn á máa ṣọ̀rẹ́.

Dáfídì jẹ́ ẹnì kan tó mọ háàpù ta dáadáa, Sọ́ọ̀lù sì máa ń gbádùn orin tó máa ń fi háàpù kọ. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan owú jíjẹ mú kí Sọ́ọ̀lù ṣe ohun búburú kan. Nígbà tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin lọ́wọ́, Sọ́ọ̀lù mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ó sì jù ú, ó wí pé: ‘Màá gún Dáfídì mọ́ ara ògiri!’ Ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà sì tàsé rẹ̀. Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù tún ju ọ̀kọ̀, àmọ́ kò tún ba Dáfídì. Ìgbà yìí gan-an ni Dáfídì wá mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ kíyè sára gidigidi.

Ṣó o rántí ìlérí tí Sọ́ọ̀lù ṣe? Ó sọ pé òun á fi ọmọbìnrin òun fún ẹni tó bá pa Gòláyátì gẹ́gẹ́ bí ìyàwó. Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé kó fẹ́ Míkálì ọmọbìnrin òun, ṣùgbọ́n ó sọ pé Dáfídì gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ pa ọgọ́rùn-ún [100] nínú àwọn Filísínì tó jẹ́ ọ̀tá wọn. Ìwọ ro ìyẹn wò ná! Ìrètí Sọ́ọ̀lù ni pé àwọn Filísínì á pa Dáfídì. Ṣùgbọ́n wọn ò rí i pa á, nítorí náà Sọ́ọ̀lù fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.

Lọ́jọ́ kan, Sọ́ọ̀lù sọ fún Jónátánì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ pa Dáfídì. Ṣùgbọ́n Jónátánì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: ‘Ẹ má pa Dáfídì lára o. Kò ṣe ohun búburú kan sí yín rí o. Dípò bẹ́ẹ̀, ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà ni gbogbo ohun tó ti ṣe jẹ́ fún yín. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nígbà tó pa Gòláyátì, nígbà tẹ́ ẹ sì rí i, inú yín dùn.’

Sọ́ọ̀lù fetí sí ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀, ó sì ṣèlérí pé òun ò ní pa Dáfídì lára. Wọ́n mú Dáfídì padà, ó sì ń sin Sọ́ọ̀lù nínú ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, lọ́jọ́ kan, nígbà tí Dáfídì ń kọrin, Sọ́ọ̀lù tún ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Dáfídì. Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà sì gún ògiri. Ẹ̀ẹ̀kẹta rèé báyìí o! Dáfídì wá mọ̀ nísinsìnyí pé òun gbọ́dọ̀ sá lọ!

Òru ọjọ́ yẹn ni Dáfídì lọ sí ilé rẹ̀. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù rán àwọn ọkùnrin kan pé kí wọ́n lọ pa á. Míkálì mọ ohun tí bàbá rẹ̀ ní lọ́kàn láti ṣe. Nítorí náà, ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: ‘Bó ò bá sá lọ lóru yìí, wàá kú kó tó di ọ̀la.’ Ní òru ọjọ́ yẹn, Míkálì ran Dáfídì lọ́wọ́ láti gba ojú fèrèsé sá lọ. Nǹkan bí ọdún méje ni Dáfídì fi ní láti máa sá pa mọ́ láti ibì kan sí òmíràn kí Sọ́ọ̀lù má bàa rí i.