Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 76

Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run

Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run

ÓJÚ ọdún mẹ́wàá lọ láti ìgbà tí Nebukadinésárì Ọba ti kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kàwé jù lọ sí Bábílónì. Nísinsìnyí, wá wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀! Wọ́n ń sun Jerúsálẹ́mù lúúlúú báyìí. Wọ́n sì ń kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò pa run lọ sí Bábílónì bí ẹrú.

Ṣé o rántí, pé ohun tí àwọn wòlíì Jèhófà ti kìlọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ bí àwọn èèyàn yẹn kò bá yí ọ̀nà búburú wọn padà rèé. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fetí sí àwọn wòlíì yẹn. Dípò kí wọ́n máa sin Jèhófà, àwọn ọlọ́run èké ni wọ́n ń sìn. Nítorí náà, àwọn èèyàn náà yẹ fún ìyà. Ìdí tá a fi mọ èyí ni pé Ìsíkíẹ́lì wòlíì Ọlọ́run sọ fún wa nípa àwọn ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.

Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Ìsíkíẹ́lì jẹ́ bí? Ó wà lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí Nebukadinésárì Ọba kó lọ sí Bábílónì ní ohun tó ju ọdún mẹ́wàá lọ kí ìparun ńlá yìí tó dé sórí Jerúsálẹ́mù. Ó tún kó Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò lọ sí Bábílónì ní àkókò kan náà.

Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ṣì wà ní Bábílónì, Jèhófà fi àwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́hùn-ún ní Jerúsálẹ́mù nínú tẹ́ńpìlì hàn án. Jèhófà ṣe èyí nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kan. Ní tòótọ́, Ìsíkíẹ́lì ṣì wà ní Bábílónì, ṣùgbọ́n Jèhófà jẹ́ kó rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì. Ohun tí Ìsíkíẹ́lì sì rí kò ṣeé máa fẹnu sọ!

Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: ‘Wo ohun ìríra tí àwọn èèyàn ń ṣe níhìn-ín nínú tẹ́ńpìlì. Wo àwọn ara ògiri tó kún fún àwòrán àwọn ejò àti ti ẹranko mìíràn. Sì wo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń jọ́sìn wọn!’ Ó ṣeé ṣe fún Ìsíkíẹ́lì láti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó sì kọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sílẹ̀.

Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Ìsíkíẹ́lì pé: ‘Ṣé o rí ohun táwọn aṣáájú Ísírẹ́lì ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè rí ìyẹn pẹ̀lú. Àwọn àádọ́rin [70] ọkùnrin ló wà níbẹ̀, gbogbo wọn ló sì ń forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run èké. Wọ́n ń wí pé: ‘Jèhófà kò rí wa. Ó ti fi ilẹ̀ yìí sílẹ̀.’

Lẹ́yìn náà ni Jèhófà fi àwọn obìnrin kan tó wà ní ẹnu ọ̀nà àríwá tẹ́ńpìlì han Ìsíkíẹ́lì. Wọ́n jókòó síbẹ̀, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún Támúsì ọlọ́run èké. Àwọn ọkùnrin kan wà ní ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì Jèhófà! Nǹkan bí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni wọ́n. Ìsíkíẹ́lì rí wọn. Wọ́n ń tẹrí ba sí ìlà oòrùn, wọ́n sì ń sin oòrùn!

Jèhófà wí pé: ‘Àwọn èèyàn wọ̀nyẹn kò ní ọ̀wọ̀ fún mi. Kì í ṣe pé wọ́n kàn ń ṣe ohun búburú nìkan ni, àní wọ́n tún wá ṣe wọ́n nínú tẹ́ńpìlì mi!’ Nítorí náà, Jèhófà lérí pé: ‘Wọn á rí agbára ìbínú mi. Mi ò sì ní káàánú fún wọn nígbà tí ìparun wọn bá dé.’

Ọdún mẹ́ta péré lẹ́yìn tí Jèhófà fi àwọn nǹkan wọ̀nyí han Ìsíkíẹ́lì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì Ọba. Nítorí náà, ó lọ gbéjà kò wọ́n. Lẹ́yìn ọdún kan àtààbọ̀, àwọn ará Bábílónì wó odi Jerúsálẹ́mù lulẹ̀ wọ́n sì sun ìlú náà jóná lúúlúú. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn yẹn ni wọ́n pa tàbí kí wọ́n kó wọn lọ bí ẹrú sí Bábílónì.

Kí ló dé tí Jèhófà fi yọ̀ọ̀da kí ìparun ńláǹlà yìí wá sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ìdí ni pé wọn ò fetí sí Jèhófà wọn ò sì pa òfin rẹ̀ mọ́. Èyí fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó fún wa nígbà gbogbo láti ṣe ohun tí Ọlọ́run bá wí.

Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n gbà fáwọn èèyàn díẹ̀ láti máa gbé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nebukadinésárì Ọba fi Júù kan tó ń jẹ́ Gẹdaláyà ṣe alábòójútó àwọn èèyàn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tún pa Gẹdaláyà. Nísinsìnyí, àwọn èèyàn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù pé àwọn ará Bábílónì máa wá tí wọ́n á sì pa gbogbo àwọn run nítorí ohun búburú tó ṣẹlẹ̀ yìí. Nítorí náà, wọ́n fi agbára mú Jeremáyà láti bá wọn lọ, wọ́n sì sá lọ sí Íjíbítì.

Èyí mú kí ilẹ̀ Ísírẹ́lì wà láìsí èèyàn kankan tí ń gbébẹ̀. Fún àádọ́rin [70] ọdún, kò sí ẹnì kankan tó gbé ilẹ̀ náà. Ó dahoro pátápátá. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti ṣe ìlérí pé òun á mú àwọn èèyàn òun padà sí ilẹ̀ náà lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún. Àmọ́ ní báyìí, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ilẹ̀ Bábílónì ní ibi tí wọ́n kó wọn lọ? Jẹ́ ká wò ó.