Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 82

Módékáì àti Ẹ́sítérì

Módékáì àti Ẹ́sítérì

JẸ́ KÁ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn kó tó di pé Ẹ́sírà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Módékáì àti Ẹ́sítérì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìjọba Páṣíà. Ẹ́sítérì ni ayaba, Módékáì arákùnrin bàbá rẹ̀ sì ni igbákejì ọba. Ẹ jẹ́ ká wo bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀ ná.

Nígbà tí Ẹ́sítérì wà lọ́mọdé jòjòló làwọn òbí rẹ̀ ti kú. Nítorí náà, Módékáì ló tọ́ ọ dàgbà. Ahasuwérúsì, ọba Páṣíà ní ààfin kan ní ìlú Ṣúṣánì, Módékáì sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tó di ọjọ́ kan, Fáṣítì ayaba ò gbọ́ràn sí ọba lẹ́nu, nítorí náà, ọba yan aya tuntun láti jẹ́ ayaba rẹ̀. Ṣó o mọ obìnrin tí ọba yàn? Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ́sítérì ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà ni.

Ṣó o rí ọkùnrin agbéraga táwọn èèyàn ń tẹrí ba fún nínú àwòrán yìí? Hámánì lorúkọ rẹ̀. Ẹni pàtàkì ló jẹ́ nílùú Páṣíà. Hámánì fẹ́ kí Módékáì, tó ò ń wò tó jókòó yẹn máa tẹrí ba fún òun pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Módékáì ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Kò rò pé ó yẹ kéèyàn máa tẹrí bá fún ọkùnrin búburú bíi ti Hámánì. Èyí mú kí Hámánì bínú gidigidi. Nítorí náà, ohun tó ṣe rèé.

Hámánì pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú ọba. Ó sọ pé: ‘Èèyàn burúkú ni wọ́n, wọn kì í ṣègbọràn sáwọn òfin rẹ. Pípa ló yẹ ká pa wọ́n run.’ Ahasuwérúsì ò mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Ẹ́sítérì aya òun. Nítorí náà, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ sí Hámánì lẹ́nu, ó sì mú kí wọ́n ṣe òfin kan pé ní ọjọ́ báyìí báyìí, kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Nígbà tí Módékáì gbọ́ nípa òfin náà, ó dààmú gidigidi. Ó rán oníṣẹ́ kan sí Ẹ́sítérì pé: ‘O gbọ́dọ̀ sọ fún ọba, kí o sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gbà wá.’ Ó lòdì sí òfin Páṣíà pé kéèyàn lọ rí ọba láìjẹ́ pé ó ní kéèyàn wá. Àmọ́, Ẹ́sítérì wọlé tọ ọba lọ láìjẹ́ pé ọba pè é. Ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i, èyí tó túmọ̀ sí pé kò ní kú. Ẹ́sítérì pe ọba àti Hámánì síbi àsè ńlá kan. Ibẹ̀ ni ọba ti béèrè lọ́wọ́ Ẹ́sítérì pé kí ni kóun ṣe fún un. Ẹ́sítérì sọ pé òun á sọ fún un bí òun àti Hámánì bá tún lè wá síbi àsè míì lọ́jọ́ kejì.

Ibi àsè náà ni Ẹ́sítérì ti sọ fún ọba pé: ‘Wọ́n ti fẹ́ pa èmi àti àwọn èèyàn mi.’ Inú bí ọba. Ó béèrè pé: ‘Ta ló fẹ́ dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò?’

Ẹ́sítérì sọ pé: ‘Ọkùnrin náà, ọ̀tá náà, ni Hámánì búburú yìí!’

Inú ti wá bí ọba gan-an wàyí. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa Hámánì. Lẹ́yìn náà, ọba sọ Módékáì di igbákejì rẹ̀. Ìgbà náà ni Módékáì rí sí i pé a ṣe òfin tuntun èyí tó fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jà fún ẹ̀mí wọn ní ọjọ́ tí wọn ì bá pa gbogbo wọn. Nítorí pé Módékáì ti di ẹni pàtàkì kó tó di ọjọ́ náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

Ìwé Ẹ́sítérì Nínú Bíbélì.