Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 79

Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún

Dáníẹ́lì Nínú Ihò Kìnnìún

Ó MÀ ṣe o? Ó dà bí ẹni pé Dáníẹ́lì ti kó sínú ìjàngbọ̀n o. Àmọ́ àwọn kìnnìún ò pà á lára! Ṣó o mọ ohun tó fà á? Ta ló ju Dáníẹ́lì sáàárín àwọn kìnnìún wọ̀nyí? Jẹ́ ká wo bọ́rọ̀ náà ṣe rí.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dáríúsì ni ọba Bábílónì báyìí. Ó fẹ́ràn Dáníẹ́lì púpọ̀ nítorí pé Dáníẹ́lì jẹ́ onínúure àti amòye. Dáríúsì yan Dáníẹ́lì ṣe olórí alákòóso nínú ìjọba rẹ̀. Èyí mú káwọn míì tí wọ́n wà nínú ìjọba náà máa jowú Dáníẹ́lì. Ohun tí wọ́n ṣe rèé.

Wọ́n tọ Dáríúsì lọ, wọ́n sì wí pé: ‘Àwa ti fohùn ṣọ̀kan Ọba, pé kí o ṣe òfin kan pé fún ọgbọ̀n ọjọ́, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan àyàfi sí ìwọ, Ọba. Bí ẹnikẹ́ni bá sì ṣe àìgbọràn, a óò ju olúwa rẹ̀ sínú ihò kìnnìún.’ Dáríúsì ò mọ̀dí táwọn èèyàn náà fi fẹ́ kóun ṣe òfin yẹn. Ṣùgbọ́n ó rò pé èrò náà ò burú, nítorí náà, ó jẹ́ kí wọ́n kọ òfin náà sínú ìwé. Lẹ́yìn ìyẹn, kò sẹ́ni tó lè yí òfin náà padà mọ́.

Nígbà tí Dáníẹ́lì gbọ́ nípa òfin náà, ó padà sílé, ó sì gbàdúrà bó ti máa ń ṣe. Àwọn ẹni ibi náà mọ̀ pé Dáníẹ́lì ò lè ṣe kó má gbàdúrà sí Jèhófà. Inú wọn dùn, torí ó dà bíi pé ọgbọ́n tí wọ́n dá láti gbẹ̀mí Dáníẹ́lì á ṣiṣẹ́.

Nígbà ti Dáríúsì Ọba mọ ìdí táwọn èèyàn náà fi fẹ́ kó ṣe òfin yẹn, inú rẹ̀ bà jẹ́. Ṣùgbọ́n kò lè yí òfin náà padà, nítorí náà ó ní láti pàṣẹ pé kí wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò àwọn kìnnìún. Ṣùgbọ́n ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: ‘Mo ní ìrètí pé Ọlọ́run rẹ tí ò ń sìn yóò gbà ọ́ là.’

Dáríúsì dààmú gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn ní òru ọjọ́ náà. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sáré lọ sẹ́nu ihò àwọn kìnnìún náà. Òun lò ń wò lókè yẹn. Ó kígbe kíkankíkan pé: ‘Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè! Ọlọ́run tí ìwọ ń sìn ha lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún bí?’

Dáníẹ́lì dáhùn pé: ‘Ọlọ́run rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì di ẹnu àwọn kìnnìún náà tí wọn kò fi lè pa mí lára.’

Inú ọba dùn gidigidi. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà. Ó wá ní kí wọ́n ju àwọn èèyàn búburú tó fẹ́ gbẹ̀mí Dáníẹ́lì sínú ihò àwọn kìnnìún náà. Kódà, kí wọ́n tiẹ̀ tó balẹ̀ sínú ihò náà làwọn kìnnìún ti hán wọn tí wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú.

Lẹ́yìn náà ni Dáríúsì Ọba wá kọ̀wé sí gbogbo èèyàn tí ń bẹ nínú ìjọba rẹ̀ pé: ‘Mo pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì. Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá. Ó pa Dáníẹ́lì mọ́ lẹ́nu àwọn kìnnìún.’