Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 81

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run

ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN èèyàn ló rin ìrìn àjò láti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ó ti dahoro pátápátá. Kò séèyàn kankan tó ń gbébẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti bẹ̀rẹ̀ sí í tún ìlú náà kọ́.

Ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ni pẹpẹ. Èyí ni ibi tí wọ́n ti lè máa fi ẹran rúbọ, tàbí tí wọ́n ti lè máa fún Jèhófà lẹ́bùn. Lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá tó ń gbé nítòsí ò fẹ́ kí wọ́n kọ́ ọ. Wọ́n gbìyànjú láti dẹ́rù bà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè ṣíwọ́. Níkẹyìn, àwọn ọ̀tá wọ̀nyí mú kí ọba Páṣíà tuntun ṣe òfin kí iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà lè dúró.

Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá. Ó ti pé ọdún mẹ́tàdínlógún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti padà láti Bábílónì. Jèhófà rán àwọn wòlíì rẹ̀ Hágáì àti Sekaráyà láti sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà padà. Àwọn èèyàn náà gbẹ́kẹ̀ lé ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ṣègbọràn sáwọn wòlíì Rẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà padà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kan wà tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, aṣojú ìjọba Páṣíà kan tó ń jẹ́ Táténáì wá, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ta ló fún wọn láṣẹ pé kí wọ́n máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà lọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún un pé ìgbà táwọn wà ní Bábílónì ni Kírúsì Ọba sọ fáwọn pé: ‘Ẹ lọ, nísinsìnyí sí Jerúsálẹ́mù kí ẹ sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, Ọlọ́run yín.’

Táténáì kọ̀wé sí Bábílónì ó sì béèrè pé ṣé lóòótọ́ ni Kírúsì tó ti dolóògbé sọ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. Láìpẹ́, ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ní Páṣíà dá èsì lẹ́tà rẹ̀ padà. Ó sì sọ níbẹ̀ pé Kírúsì sọ bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́. Ni ọba bá kúkú kọ̀wé pé: ‘Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wọn. Mo sì pàṣẹ fún yín pé kí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́.’ Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí, inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dùn.

Ọ̀pọ̀ ọdún tún kọjá lọ lẹ́yìn náà. Ó sì ti ń tó bí ọdún méjìdínláàádọ́ta báyìí tí wọ́n ti parí tẹ́ńpìlì náà. Tálákà làwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ìlú wọn àti tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ò sì lẹ́wà púpọ̀. Níbi tí Ẹ́sírà tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì wà ní Bábílónì lọ́hùn-ún ló ti gbọ́ pé tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ń fẹ́ àtúnṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe?

Ẹ́sírà tọ Atasásítà ọba Páṣíà lọ, ọba rere yìí sì fún Ẹ́sírà ní ẹ̀bùn púpọ̀ láti mú lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ẹ́sírà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Bábílónì ran òun lọ́wọ́ láti kó àwọn ẹ̀bùn náà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nǹkan bí ẹgbàáta [6,000] èèyàn yọ̀ǹda láti lọ. Ọ̀pọ̀ fàdákà àti wúrà àtàwọn ohun iyebíye mìíràn ló wà tí wọ́n ní láti kó dání lọ.

Ọkàn Ẹ́sírà ò balẹ̀ nítorí pé àwọn èèyàn búburú wà lójú ọ̀nà. Àwọn èèyàn wọ̀nyí lè gba fàdákà àti wúrà wọn, kí wọ́n sì pa wọ́n. Nítorí náà, Ẹ́sírà pe àwọn èèyàn náà pa pọ̀ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bò àwọn lọ sí Jerúsálẹ́mù.

Jèhófà sì dáàbò bò wọ́n. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tí wọ́n ti wà lórí ìrìn, wọ́n dé Jerúsálẹ́mù ní àlàáfíà. Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn pé Jèhófà lè dáàbò bo àwọn tó bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó lè ran àwọn lọ́wọ́?