ÌTÀN 83
Odi Jerúsálẹ́mù
WO GBOGBO iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ nínú àwòrán yìí. Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dí lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ odi Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Nebukadinésárì Ọba pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún méjìléláàádọ́jọ [152] sẹ́yìn, ó wó àwọn odi lulẹ̀ ó sì fi iná sun àwọn ẹnu ọ̀nà odi. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò tún àwọn odi náà kọ́ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé láti Bábílónì.
Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn tó ń gbé inú ìlú náà láti àwọn ọdún wọ̀nyẹn wá, láìsí ògiri kankan tó yí ìlú wọn ká? Inú ewu ni wọ́n wà. Ó máa rọrùn fáwọn ọ̀tá wọn láti wọlé tọ̀ wọ́n wá kí wọ́n sì kọ lù wọ́n. Àmọ́, ní báyìí o, ọkùnrin tó ń jẹ́ Nehemáyà yìí ti ṣe tán láti ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti tún àwọn odi náà kọ́. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ Nehemáyà?
Nehemáyà jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kan tó wá láti ìlú Ṣúṣánì níbi tí Módékáì àti Ẹ́sítérì ń gbé. Ààfin ọba ni Nehemáyà ti ń siṣẹ́, nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀rẹ́ Módékáì àti Ẹ́sítérì Ayaba. Ṣùgbọ́n Bíbélì ò sọ pé Nehemáyà ṣiṣẹ́ fún Ahasuwérúsì Ọba tó jẹ́ ọkọ Ẹ́sítérì o. Ọba tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀, ìyẹn Atasásítà Ọba, ló siṣẹ́ fún.
Bó o bá rántí, Atasásítà ni ọba rere tó fún Ẹ́sírà ní gbogbo owó tí wọ́n mú padà lọ sí Jerúsálẹ́mù láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ṣùgbọ́n Ẹ́sírà ò kọ́ àwọn ògiri tó wó lulẹ̀ nínú ìlú náà. Jẹ́ ká wá wo bó ṣe jẹ́ tó fi di pé Nehemáyà ló ṣe iṣẹ́ náà.
Ó ti pé ọdún mẹ́tàlá [13] géérégé tí Atasásítà ti fún Ẹ́sírà lówó pé kó fi kọ́ tẹ́ńpìlì. Ní báyìí, Nehemáyà ni olórí agbọ́tí fún Atasásítà Ọba. Èyí túmọ̀ sí pé ó ń gbé wáìnì fún ọba, ó sì ń rí i dájú pé ẹnikẹ́ni ò gbìyànjú láti fún ọba ní májèlé jẹ. Iṣẹ́ pàtàkì ló ń ṣe.
Nígbà tó di ọjọ́ kan, Hánáánì arákùnrin Nehemáyà àtàwọn míì láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì wá bẹ Nehemáyà wò. Wọ́n sọ fún un nípa ìṣòro táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àti bó ṣe jẹ́ pé àwọn odi Jerúsálẹ́mù ṣì wà ní wíwó lulẹ̀. Èyí mú kí inú Nehemáyà bà jẹ́ gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un náà.
Lọ́jọ́ kan, ọba ṣàkíyèsí pé inú Nehemáyà ò dùn, ó sì bi í pé: ‘Kí ló dé tó o fajú ro?’ Nehemáyà sọ fún un pé nítorí pé ipò tí Jerúsálẹ́mù wà ò dáa lòun fi fajú ro. Ó ní àwọn ògiri rẹ̀ ṣì wà ní wíwó lulẹ̀. Ọba wá bi í pé: ‘Kí lò ń fẹ́?’
Nehemáyà sọ fún ọba pé: ‘Jẹ́ kí n lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí n lè tún àwọn odi rẹ̀ kọ́.’ Onínúure èèyàn ni Atasásítà Ọba. Ó fún Nehemáyà ní àyè láti lọ, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti rí igi fún ṣíṣe díẹ̀ lára iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Nehemáyà fi lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì sọ ohun tó ń gbèrò láti ṣe fáwọn èèyàn. Wọ́n fara mọ́ èrò náà, wọ́n sì wí pé: ‘Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ ilé kíkọ́.’
Nígbà táwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí bí ògiri tí wọ́n ń kọ́ náà ṣe ń ga ròkè, wọ́n sọ pé: ‘Àwa yóò gòkè lọ, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró.’ Ọ̀rọ̀ yìí dé etígbọ̀ọ́ Nehemáyà, ó sì fún àwọn òṣìṣẹ́ náà ní idà àti ọ̀kọ̀. Ó wí pé: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ọ̀tá wa. Ẹ jà nítorí àwọn arákùnrin yín, nítorí àwọn ọmọ yín, nítorí àwọn aya yín àti nítorí ilé yín.’
Àwọn èèyàn náà ní ìgboyà. Ohun ìjà wọn ò yà wọ́n lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń mọ ògiri náà lọ. Láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta [52] péré, wọ́n ti parí iṣẹ́ náà. Ọkàn àwọn èèyàn tó wà nínú ìlú náà wá balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ wàyí. Nehemáyà àti Ẹ́sírà kọ́ àwọn èèyàn náà ní òfin Ọlọ́run, inú àwọn èèyàn náà sì dùn.
Síbẹ̀ àwọn nǹkan yàtọ̀ sí bó ṣe rí kó tó di pé àwọn ará Bábílónì wá kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́rú. Ọba Páṣíà ló ń ṣàkóso lé àwọn èèyàn náà lórí wọ́n sì gbọ́dọ̀ sìn ín. Àmọ́, Jèhófà ti ṣèlérí pé òún á rán ọba tuntun kan wá, àti pé ọba yìí yóò mú àlàáfíà wá fún àwọn èèyàn. Ta ni ọba yìí? Báwo ló ṣe máa mú àlàáfíà wá sáyé? Nǹkan bí àádọ́ta lé ní irínwó [450] ọdún kọjá ká tó tún gbọ́ ohunkóhun nípa èyí. Lẹ́yìn náà ni ìbímọ pàtàkì kan wáyé. Àmọ́, ìtàn mìíràn nìyẹn ṣá o.