Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 80

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Kúrò Ní Bábílónì

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Kúrò Ní Bábílónì

ÓTI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì báyìí táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ti ṣẹ́gun Bábílónì. Sì wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ń wò tí wọ́n ń kúrò ní Bábílónì yìí o. Báwo ni wọ́n ṣe dòmìnira? Ta ló ní kí wọ́n máa lọ?

Kírúsì, ọba Páṣíà ni. Kí wọ́n tó lálàá pé wọ́n máa bí Kírúsì ni Jèhófà ti mú kí wòlíì Aísáyà kọ̀wé nípa rẹ̀ báyìí pé: ‘Ìwọ yóò ṣe ohun tí mo fẹ́ kí o ṣe gan-an. Àwọn ilẹ̀kùn yóò ṣí sílẹ̀ fún ọ láti ṣẹ́gun ìlú náà.’ Kírúsì náà ló sì jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́gun Bábílónì. Àwọn ará Mídíà àti Páṣíà gba àwọn ẹnu ọ̀nà tó ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ wọnú ìlú náà lóru.

Ṣùgbọ́n Aísáyà wòlíì Jèhófà tún sọ pé Kírúsì yóò pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́. Ṣé Kírúsì pàṣẹ yìí fún wọn? Bẹ́ẹ̀ ni. Kírúsì sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ lọ, nísinsìnyí, sí Jerúsálẹ́mù kí ẹ sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, Ọlọ́run yín.’ Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nínú àwòrán yìí ń lọ ṣe gan-an nìyẹn.

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló lè rin ọ̀nà tó jìn náà padà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀nà náà jìn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ibùsọ̀ [500] (ìyẹn ẹgbẹ̀rin [800] kìlómítà), ọ̀pọ̀ nínú wọn ti darúgbó jù, ara àwọn míì ò sì dá ṣáṣá tó láti rin ìrìn tó jìn tó bẹ́ẹ̀. Àwọn ìdí mìíràn sì wà táwọn kan ò fi lọ. Àmọ́, Kírúsì sọ fáwọn tí kò lọ pé: ‘Ẹ fi fàdákà àti wúrà àti àwọn ẹ̀bùn mìíràn fún àwọn tó ń padà lọ láti kọ́ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀.’

Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ni wọ́n kó fáwọn tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù. Yàtọ̀ síyẹn, Kírúsì fún wọn ní àwọn àwo àti ife tí Nebukadinésárì kó láti inú tẹ́ńpìlì Jèhófà nígbà tó pa Jerúsálẹ́mù run. Wọ́n ní ohun púpọ̀ láti kó padà lọ.

Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rìnrìn àjò fún nǹkan bí oṣù mẹ́rin, wọ́n dé Jerúsálẹ́mù ní àkókò tó yẹ. Ó ti di àádọ́rin [70] ọdún géérégé tí ìlú náà ti pa run, ilẹ̀ náà sì wà ní ahoro pátápátá láìsí olùgbé. Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti padà sí ìlú wọn báyìí, ìṣòro ń bẹ níwájú wọn gẹ́gẹ́ bá a ò ṣe rí nínú ìtàn tó kàn.