Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 77

Wọ́n Kọ̀ Láti Tẹrí Ba

Wọ́n Kọ̀ Láti Tẹrí Ba

ǸJẸ́ o rántí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́ta yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ni ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì tó kọ̀ láti jẹ ohun tí wọ́n mọ̀ pé kò yẹ káwọn jẹ. Àwọn ará Bábílónì máa ń pè wọ́n ní Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Àmọ́, tún wo ibi tí wọ́n wà báyìí. Kí ló dé tí wọn ò fi ṣe bíi tàwọn èèyàn yòókù káwọn náà sì tẹrí ba fún ère gogoro yìí? Jẹ́ ká wo nǹkan tó fà á ná.

Ṣó o rántí òfin tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ kọ tá à ń pè ní Òfin Mẹ́wàá? Èyí àkọ́kọ́ nínú àwọn òfin náà sọ pé: ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún ọlọ́run èyíkéyìí yàtọ̀ sí mi.’ Òfin táwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ń ṣègbọràn sí nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn.

Nebukadinésárì, ọba Bábílónì ti ké sí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn pé kí wọ́n wá bọlá fún ère tó gbé kalẹ̀ yìí. Ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà tán ni pé: ‘Nígbà tẹ́ ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, háàpù àtàwọn ohun èlò ìkọrin mìíràn, ẹ gbọ́dọ̀ wólẹ̀ kẹ́ ẹ sì jọ́sìn ère wúrà yìí. Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹrí bá kó sì jọ́sìn rẹ̀ ni a óò sọ sínú ìléru gbígbóná tí ń jó.’

Nígbà tí Nebukadinésárì gbọ́ pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò tẹrí ba, inú bí i gan-an. Ó pàṣẹ pé kí wọn kó wọ́n wá sọ́dọ̀ òun. Ó tún fún wọn láyè lẹ́ẹ̀kan sí i kí wọ́n bàa lè tẹrí ba fún èrè náà. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Wọ́n sọ fún Nebukadinésárì pé: ‘Ọlọ́run wa tí àwa ń sìn lè gbà wá. Bó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé kò gbà wá, a ò ní tẹrí ba fún ère wúrà rẹ.’

Nígbà tí Nebukadinésárì gbọ́rọ̀ tí wọ́n sọ yìí, inú túbọ̀ bí i. Iná ìléru kan ń bẹ nítòsí ó sì pàṣẹ pé: ‘Ẹ mu kí ìléru náà gbóná sí i nígbà méje ju bó ṣe máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ!’ Lẹ́yìn náà ló ní káwọn gìrìpá lára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kí wọ́n sì sọ wọ́n sínú ìléru náà. Ìléru náà gbóná tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ooru rẹ̀ fi pa àwọn gìrìpá náà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n jù sínú ìléru náà?

Ọba wo inú ìléru náà, ẹ̀rù sì bà á púpọ̀. Ó béèrè pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn ọkùnrin mẹ́ta la dè tá a sì sọ sínú ìléru oníná tí ń jó ni?’

Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn mẹ́ta la sọ sínú iná.’

Ọba wá sọ pé: ‘Ṣùgbọ́n ọkùnrin mẹ́rin ni mo rí tí wọ́n ń rìn káàkiri fàlàlà nínú iná náà. Okùn tí wọ́n fi dè wọ́n ti tú, bẹ́ẹ̀ ni iná náà ò jó wọn. Ẹnì kẹrin sì rí bí áńgẹ́lì.’ Ọba sún mọ́ ilẹ̀kùn ìléru oníná náà ó sì kígbe pé: ‘Ṣádírákì! Méṣákì! Àbẹ́dínígò! Ẹ jáde síta kẹ́ ẹ sì máa bọ̀ wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Ju Lọ!’

Nígbà tí wọ́n jáde síta, gbogbo wọn rí i pé iná náà ò rà wọ́n lára rárá. Ọba wá sọ pé: ‘Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò! Ó ti rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì ti gbà wọ́n là nítorí tí wọ́n kọ̀ láti tẹrí ba kí wọ́n sì jọ́sìn ọlọ́run mìíràn àyàfi Ọlọ́run wọn.’

Bá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ǹjẹ́ irú àpẹẹrẹ yẹn kọ́ ló yẹ káwa náà tẹ̀ lé?