Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 101

Wọ́n Pa Jésù

Wọ́n Pa Jésù

WO NǸKAN búburú tó ń ṣẹlẹ̀ yìí! Jésù ni wọ́n ń pa yìí. Wọ́n ti gbé e kọ́ sórí igi. Wọ́n kan ìṣó mọ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Kí ló dé ti wọ́n fi ṣe irú nǹkan yìí sí Jésù?

Ó jẹ́ nítorí pé àwọn kan kórìíra Jésù ni. Ǹjẹ́ o mọ àwọn ẹni náà? Ọ̀kan nínú wọn ni áńgẹ́lì búburú náà, ìyẹn Sátánì Èṣù. Òun ló jẹ́ kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Sátánì sì lẹni tó mú káwọn ọ̀tá Jésù hu ìwà búburú yìí.

Ṣáájú kí wọ́n tó kan Jésù mọ́ igi, àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti fi onírúuru ìwọ̀sí lọ̀ ọ́. Ṣó o rántí bí wọ́n ṣe wá sí ọgbà Gẹtisémánì tí wọ́n sì mú un lọ? Àwọn wo làwọn ọ̀tá wọ̀nyí? Àwọn aṣáájú ìsìn kúkú ni. Jẹ́ ká wá wo ohun tó tún ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e.

Nígbà táwọn aṣáájú ìsìn mú Jésù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sá lọ. Wọ́n fi Jésù sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà wọ́n. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù kò lọ jìnnà. Wọ́n ń tẹ̀ lé wọn láti rí ohun tó máa ṣe Jésù.

Àwọn àlùfáà mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì ọkùnrin arúgbó kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ àlùfáà àgbà. Àwọn èèyàn yìí ò dúró pẹ́ níbẹ̀. Wọ́n wá mú Jésù lọ sí ilé Káyáfà, tó jẹ́ àlùfáà àgbà báyìí. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ti pé jọ sínú ilé rẹ̀.

Nínú ilé Káyáfà wọ́n ṣe ìgbẹ́jọ́ kan. Wọ́n mú àwọn èèyàn wá láti purọ́ mọ́ Jésù. Gbogbo àwọn aṣáájú sì wí pé: ‘Ó yẹ kí wọ́n pa Jésù.’ Ìgbà náà ni wọ́n tutọ́ sí i lójú, wọ́n sì gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́.

Nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, Pétérù wà lóde ní àgbàlá. Ìgbà òtútù ni lóru, torí náà àwọn èèyàn dá iná. Bí wọ́n ti ń yá iná lọ́wọ́, obìnrin kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ wo Pétérù, ó sì wí pé: ‘Ọkùnrin yìí máa ń wà pẹ̀lú Jésù.’

Pétérù dáhùn pé ‘Ó tì o, èmi kọ́!’

Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ń sọ fún Pétérù pé ó máa ń wà pẹ̀lú Jésù. Ṣùgbọ́n ẹ̀ẹ̀mẹtẹ̀ẹ̀ta ni Pétérù sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ̀ rárá. Nígbà kẹta tí Pétérù sọ báyìí, Jésù yíjú padà ó sì wò ó lójú. Pétérù kábàámọ̀ fún irọ́ tó pa, ó sì jáde láti lọ sunkún.

Bí oòrun ti ń yọ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Friday, àwọn àlùfáà mú Jésù wá sí ibi ìpàdé ńlá, ìyẹn inú gbọ̀ngàn ilé ẹjọ́ àwọn Sànhẹ́dírìn. Ibẹ̀ ni wọ́n ti jíròrò ohun tí wọ́n máa ṣe fún Jésù. Wọ́n wá mú un lọ sọ́dọ̀ Pọ́ńtù Pílátù, alákòóso àgbègbè Jùdíà.

Àwọn àlùfáà sọ́ fún Pílátù pé: ‘Èèyànkéèyàn ni ọkùnrin yìí. Ó gbọ́dọ̀ kú.’ Pílátù béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ Jésù, lẹ́yìn náà, ó sọ pé: ‘Èmi kò rí nǹkan kan tí ọkùnrin yìí ṣe.’ Ìgbà náà ni Pílátù fi Jésù ránṣẹ́ sí Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Hẹ́rọ́dù ni alákòóso Gálílì, àmọ́ Jerúsálẹ́mù ló wà. Hẹ́rọ́dù pẹ̀lú kò rí i pé Jésù ṣe ohun búburú kankan, nítorí náà, ó tún dá a padà sọ́dọ̀ Pílátù.

Pílátù fẹ́ láti dá Jésù sílẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá Jésù fẹ́ kó dá ẹlẹ́wọ̀n mìíràn sílẹ̀ dípò rẹ̀. Bárábà ni ọlọ́ṣà náà. Ó tí di ọ̀sán gangan báyìí nígbà tí Pílátù mú Jésù jáde wá. Ó sọ fún àwọn èèyàn yẹn pé: ‘Ẹ wo ọba yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà náà kígbe pé: ‘Ẹ mú un kúrò! Ẹ pa á! Ẹ pa á!’ Nítorí náà Pílátù dá Bárábà sílẹ̀, wọ́n sì mú Jésù lọ láti pa á.

Ọ̀sán ọjọ́ Friday ni wọ́n kan Jésù mọ́ igi. Àwọn ọ̀daràn méjì mìíràn tí wọ́n kan àwọn pẹ̀lú mọ́gi wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àti òsì Jésù, àwòrán wọn ò yọ níbí. Kó tó di pé Jésù kú, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn yẹn sọ fún un pé: ‘Rántí mi nígbà tó o bá dé inú ìjọba rẹ.’ Jésù dáhùn pé: ‘Mo ṣèlérí fún ọ pé o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.’

Ǹjẹ́ ìlérí àgbàyanu kọ́ lèyí? Ṣó o mọ Párádísè tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ibo ni Párádísè tí Ọlọ́run dá ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wà? Orí ilẹ̀ ayé ni. Nígbà tí Jésù bá sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní ọ̀run, ó máa jí ọkùnrin yìí dìde láti gbádùn Párádísè lórí ilẹ̀ ayé tuntun. Ǹjẹ́ èyí ò mú inú wa dùn?