Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 86

Àwọn Ọkùnrin Tí Ìràwọ̀ Kan Darí

Àwọn Ọkùnrin Tí Ìràwọ̀ Kan Darí

ǸJẸ́ o rí ìràwọ̀ tó ń tàn yanran tí ọkùnrin kan ń nawọ́ sí yẹn? Ìgbà tí wọ́n kúrò ní Jerúsálẹ́mù ni ìràwọ̀ yìí yọ. Àti Ìlà Oòrùn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti wá, ìràwọ̀ ni wọ́n sì máa ń wádìí nípa rẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé ìràwọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ yìí ń darí àwọn lọ sọ́dọ̀ ẹni pàtàkì kan.

Nígbà táwọn ọkùnrin wọ̀nyí dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n béèrè pé: ‘Ibo ni ọmọ náà tó máa jẹ́ ọba àwọn Júù wà?’ “Júù” ni orúkọ mìíràn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jẹ́. Àwọn ọkùnrin yẹn wí pé: ‘A ti kọ́kọ́ rí ìràwọ̀ ọmọ yìí nígbà tá a wà ní Ìlà Oòrùn, a sì wá láti forí balẹ̀ fún un.’

Ìgbà tí Hẹ́rọ́dù, tí í ṣe ọba ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ èyí, ara ẹ̀ ò balẹ̀ mọ́. Kò fẹ́ kí ọba mìíràn gba ipò òun. Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù pe àwọn olórí àlùfáà ó sì béèrè pé: ‘Ibo ni wọ́n ti máa bí ọba tí Bíbélì ṣèlérí yẹn?’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Bíbélì wí pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.’

Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù pe àwọn ọkùnrin tó ti Ìlà Oòrùn wá yẹn ó sì wí pé: ‘Ẹ lọ wá ọmọ kékeré yẹn kàn. Tẹ́ ẹ bá sì ti rí i, ẹ jẹ́ kí n gbọ́. Èmi náà fẹ́ lọ forí balẹ̀ fún un.’ Àmọ́ ohun tí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ ni pé kó rí ọmọ yẹn kó bàa lè pa á!

Ìràwọ̀ yẹn wá ṣáájú àwọn ọkùnrin náà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì dúró lórí ibi tí ọmọ náà wà. Ìgbà tí wọ́n wọ inú ilé yẹn, wọ́n rí Màríà àti ọmọ ọwọ́ náà Jésù. Wọ́n kó ẹ̀bùn jáde wọ́n sì fi wọ́n fún Jésù. Jèhófà wá kìlọ̀ fún wọn lójú àlá lẹ́yìn náà pé kí wọ́n má ṣe padà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù. Nítorí náà, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn padà sí orílẹ̀-èdè wọn.

Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé àwọn ọkùnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn wọ̀nyẹn ti padà sí ìlú wọn, inú bí i púpọ̀. Ó wá pa àṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti tètè kìlọ̀ fún Jósẹ́fù lójú àlá, Jósẹ́fù sì lọ sí Íjíbítì pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ pé Hẹ́rọ́dù ti kú, ó mú Màríà àti Jésù padà sí Násárétì ìlú wọn. Ibí yìí ni Jésù ti dàgbà.

Ta lo rò pé ó mú kí ìràwọ̀ tuntun yẹn tàn? Má gbàgbé pé àwọn ọkùnrin náà kọ́kọ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n ti rí ìràwọ̀ yẹn. Sátánì Èṣù fẹ́ láti pa Ọmọ Ọlọ́run, ó sì mọ̀ pé Hẹ́rọ́dù Ọba Jerúsálẹ́mù máa gbìyànjú láti pa á. Nítorí náà, Sátánì ló ní láti jẹ́ ẹni tó mú kí ìràwọ̀ yẹn tàn.