Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 90

Pẹ̀lú Obìnrin Kan Lẹ́bàá Kànga

Pẹ̀lú Obìnrin Kan Lẹ́bàá Kànga

JÉSÙ dúró sinmi lẹ́bàá kànga kan ní Samáríà. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ láti ra oúnjẹ nínú ìlú. Omi ni obìnrin tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ yìí wá pọn. Jésù wí fún un pé: ‘Fún mi ní omi mu.’

Èyí ya obìnrin yẹn lẹ́nu púpọ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀? Ìdí ni pé Júù ni Jésù, ará Samáríà sì ni obìnrin yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ni ò sì fẹ́ràn àwọn ará Samáríà. Wọn kì í tiẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀! Àmọ́ Jésù fẹ́ràn gbogbo onírúurú èèyàn. Torí náà, ó sọ pé: ‘Ká ní o mọ ẹni tó ń tọrọ omi lọ́wọ́ rẹ ni, wàá tọrọ omi iyè lọ́wọ́ rẹ̀ á sì fún ẹ ní omi tó ń fún èèyàn ní ìyè.’

Obìnrin yẹn sọ pé: ‘Ọ̀gá, kànga yìí jìn púpọ̀ o, bẹ́ẹ̀ ẹ sì tún ní garawa. Ibo lẹ ti máa rí omi tó ń fún èèyàn ní ìyè yìí?’

Jésù ṣàlàyé fún un pé: ‘Bó o bá mu omi inú kànga yìí, òùngbẹ á ṣì máa gbẹ ọ́. Àmọ́ omi tí màá fún èèyàn lè mú kéèyàn wà láàyè títí láé.’

Obìnrin yẹn wí pé: ‘Ọ̀gá, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún mi ní omi tẹ́ ẹ̀ ń wí yìí! Nípa bẹ́ẹ̀, òùngbẹ ò tún ní gbẹ mí mọ́. Mi ò sì tún ní máa wá síbí wá pọn omi mọ́.’

Omi gidi ni obìnrin yẹn rò pé Jésù ń sọ. Àmọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ṣe ni òtítọ́ yìí dà bí omi tó ń fún èèyàn ní ìyè. Ó lè fún èèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Ni Jésù bá sọ fún obìnrin yẹn pé: ‘Lọ pe ọkọ rẹ wá.’

Obìnrin náà dáhùn pé: ‘Mi ò ní ọkọ.’

Jésù sọ pé: ‘Òótọ́ ni ìdáhùn rẹ. Ṣùgbọ́n o ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tó o sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nísinsìnyí kì í ṣe ọkọ rẹ.’

Ẹnu ya obìnrin yìí gidigidi torí pé òtítọ́ ni gbogbo èyí. Báwo ni Jésù ṣe mọ gbogbo nǹkan yìí? Jésù mọ̀ ọ́n torí pé Jésù ni Ẹni Ìlérí náà tí Ọlọ́run rán wá, Ọlọ́run ló sì sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún un. Àkókò yìí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin ará Samáríà sọ̀rọ̀.

Kí ni gbogbo èyí kọ́ wa? Ó fi hàn pé Jésù máa ń ṣe dáadáa sí gbogbo onírúurú èèyàn. Àwa náà sì gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúure pẹ̀lú. Kò yẹ ká máa ronú pé àwọn èèyàn kan ò dáa nítorí pé wọ́n wá látinú ìran tàbí ẹ̀yà míì. Jésù fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ òtítọ́ tó ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Àwa náà sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.