Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 94

Jésù Fẹ́ràn Àwọn Ọmọdé

Jésù Fẹ́ràn Àwọn Ọmọdé

WO JÉSÙ níhìn-ìn bó ṣe fọwọ́ gbá ọmọdé yìí mọ́ra. O lè sọ lóòótọ́ pé Jésù ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé kún. Àwọn tó ń wò ó yẹn làwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Kí ni Jésù ń bá wọn sọ? Jẹ́ ká wádìí rẹ̀ wò.

Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ìrìn-ọ̀nà jíjìn ni. Lójú ọ̀nà, àwọn àpọ́sítélì ti ń bá ara wọn jiyàn. Nítorí náà, lẹ́yìn ìrìn àjò yẹn Jésù bi wọ́n léèrè pé: ‘Kí lẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?’ Lóòótọ́ o, Jésù mọ ohun tí wọ́n ń jiyàn lé lórí. Ṣùgbọ́n ó béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ wọn láti wò ó bóyá wọ́n á sọ ọ́ fún òun.

Àwọ́n àpọ́sítélì kò dáhùn, torí pé lójú ọ̀nà, ohun tí wọ́n ń jiyàn lé lórí ni ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. Àwọ́n àpọ́sítélì kan fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì ju àwọn míì lọ. Báwo ni Jésù á ṣe sọ fún wọn pé kò tọ́ láti jẹ́ ẹni títóbi jù lọ o?

Ó pe ọmọdékùnrin yìí, ó sì mú un dúró níwájú gbogbo wọn. Ó sọ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ èyí dájú, àyàfi bẹ́ ẹ bá yí padà, kẹ́ ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé, ẹ ò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run láé. Ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba yẹn ni ẹni tó bá sọ ara rẹ̀ dà bí ọmọ kékeré yìí.’ Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀ tí Jésù fi sọ báyìí?

Ìdí ni pé kò sóhun tó kan àwọn ọmọdé nípa ìfẹ́ láti jẹ́ ẹni ńlá tó ṣe pàtàkì ju àwọn mìíràn lọ. Nítorí náà, àwọn àpọ́sítélì ní láti kẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí àwọn ọmọdé lọ́nà yìí kí wọ́n má sì ṣe bá ara wọn jà lórí ọ̀ràn jíjẹ́ ẹni tó ṣé pàtàkì jù.

Àwọ́n ìgbà mìíràn wà pẹ̀lú, tí Jésù fi hàn bí òun ṣe ka àwọn ọmọdé sí tó. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà àwọn kan gbé àwọn ọmọ wọn wá láti rí Jésù. Àwọn àpọ́sítélì gbìyànjú láti lé wọn padà. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: ‘Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn dúró, ti àwọn èèyàn tó dà bíi wọn ni Ìjọba Ọlọ́run.’ Jésù sì gbé àwọn ọmọdé yẹn sí apá rẹ̀, ó sì súre fún wọn. O ò rí pé ó dáa tá a mọ̀ pé Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọdé?