Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN 91

Jésù Kọ́ Àwọn Èèyàn Lórí Òkè

Jésù Kọ́ Àwọn Èèyàn Lórí Òkè

JÉSÙ ló jókòó yẹn. Ó ń kọ́ gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí lórí òkè kan ní Gálílì. Àwọn tó jókòó sún mọ́ ọn wọ̀nyẹn làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó yan méjìlá [12] nínú wọn láti jẹ́ àpọ́sítélì. Àwọn àpọ́sítélì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàtàkì. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ wọn?

Símónì Pétérù àti Áńdérù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò wà nínú wọn. Jákọ́bù àti Jòhánù táwọn pẹ̀lú jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò wà lára wọn. Àpọ́sítélì mìíràn tún wà tó ń jẹ́ Jákọ́bù, òmíràn sì tún wà tó ń jẹ́ Símónì. Àwọn méjì ló ń jẹ́ Júdásì. Èyí àkọ́kọ́ ni Júdásì Ísíkáríótù, èkejì la tún ń pè ní Tádéọ́sì. Fílípì àti Nàtáníẹ́lì (tó tún ń jẹ́ Bátólómíù) wà tó fi mọ́ Mátíù àti Tọ́másì.

Lẹ́yìn tí Jésù ti Samáríà dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún ìgbà àkọ́kọ́ pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tí ìjọba yẹn jẹ́? Ìjọba gidi ti Ọlọ́run ni. Jésù ni ọba rẹ̀. Láti ọ̀run láá ti máa ṣàkóso á sì mú àlàáfíà wá sí ayé. Ìjọba Ọlọ́run á sọ gbogbo ayé di Párádísè ẹlẹ́wà.

Ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn níbí yìí. Ó ṣàlàyé pé, ‘Bí ẹ óò ti máa gbàdúrà nìyí: Bàbá wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, bíi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ ‘Àdúrà Olúwa’ ni ọ̀pọ̀ máa ń pè é. Àwọn míì máa ń pè é ní ‘Bàbá Wa Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run.’ Ǹjẹ́ o lè ka gbogbo àdúrà yẹn?

Jésù tún ń kọ́ àwọn èèyàn yẹn ní bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn ẹlòmíì. Ó sọ pé: ‘Ṣe fún àwọn ẹlòmíràn ohun tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe fún ọ.’ Ṣé ìwọ náà ò fẹ́ káwọn ẹlòmíràn máa ṣe dáadáa sí ẹ? Nítorí náà, ohun tí Jésù ń wí ni pé, a ní láti máa ṣe dáadáa sáwọn ẹlòmíì. Nígbà tí gbogbo èèyàn bá wá ń ṣe báyìí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ǹjẹ́ o ò rí i pé nǹkan á dáa gan-an?