Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 7

Ìgbà Tí Jésù Jíǹde sí Ìgbà Tí Wọ́n Ju Pọ́ọ̀lù Sẹ́wọ̀n

Ìgbà Tí Jésù Jíǹde sí Ìgbà Tí Wọ́n Ju Pọ́ọ̀lù Sẹ́wọ̀n

Ní ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde. Lọ́jọ́ yẹn, ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ogójì [40] ọjọ́ ló sì fi ń fara hàn wọ́n. Lẹ́yìn náà, níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ń wò ó, ó gòkè lọ sọ́run. Ní ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ọ̀tá Ọlọ́run mú káwọn èèyàn gbé àwọn àpọ́sítélì jù sẹ́wọ̀n. Àwọn alátakò sọ Sítéfánù lókùúta pa. Àmọ́, a óò rí bí Jésù ṣe yan ọ̀kan lára àwọn alátakò náà láti di ìránṣẹ́ rẹ̀ pàtàkì. Ẹni náà ló di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ní ọdún mẹ́ta ààbọ̀ lẹ́yìn ikú Jésù, Ọlọ́run rán àpọ́sítélì Pétérù pé kó lọ wàásù fún ọkùnrin kan tí kì í ṣe Júù, ìyẹn ni Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ àkọ́kọ́. Nígbà ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tímótì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a rìnrìn àjò. A óò rí bí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò ṣe ní ìrírí tó mọ́kàn wọn yọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. Níkẹyìn, wọ́n ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n dá a sílẹ̀, àmọ́ wọ́n tún padà jù ú sẹ́wọ̀n wọ́n sì pa á. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ohun tó lé lọ́dún méjìlélọ́gbọ̀n [32] ló wà nínú APÁ 7 yìí.

 

NÍ APÁ YÌÍ

ÌTÀN 102

Jésù Jíǹde

Lẹ́yìn ti áńgẹ́lì kan yí òkúta kúrò ní ibojì Jésù, ohun tí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ibẹ̀ rí yà wọ́n lẹ́nu gan-an.

STORY 103

Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa

Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò dá a mọ̀ lẹ́yìn tó jíǹde?

ÌTÀN 104

Jésù Pa Dà Sọ́run

Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àṣẹ pàtàkì kan.

ÌTÀN 105

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dúró Sí Jerúsálẹ́mù

Kí ló dé tí Jésù tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ntíkọ́sì?

ÌTÀN 106

Ìdáǹdè Kúrò Nínú Túbú

Àwọn aṣáájú ìsìn Júù fi àwọn ápọ́sítélì sẹ́wọ̀n kí wọ́n má bàa wàásù mọ́, àmọ́ Ọlọ́run ní ohun míì lọ́kàn tó fẹ́ ṣe.

ÌTÀN 107

Wọ́n Sọ Sítéfánù Lókùúta Pa

Nígbà tí wọ́n ń pa Sítéfánù, ó gba àdúrà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

ÌTÀN 108

Lójú Ọ̀nà Damásíkù

Iná tó ń fọ́ni lójú àti ohùn kan tó dún láti ọ̀run yí ìgbésí ayé Sọ́ọ̀lù pa dà.

ÌTÀN 109

Pétérù Lọ Sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù

Ṣé Ọlọ́run ka ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè kan sí ju òmíràn lọ?

ÌTÀN 110

Tímótì—Olùrànlọ́wọ́ Tuntun fún Pọ́ọ̀lù

Tímótì fi àwọn ẹbí rẹ̀ sílẹ̀ kó lè lọ máa wàásù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù.

ÌTÀN 111

Ọmọkùnrin Kan Tó Sùn Lọ

Yútíkọ́sì sùn lọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ àsọyé àkọ́kọ́, àmọ́ kò sùn lọ nígbà àsọyé kejì. Iṣẹ́ ìyanu ńlá kan ṣẹlẹ̀ láàárín àsọyé méjèèjì.

ÌTÀN 112

Ọkọ̀ Rì Ní Erékùṣù Kan

Nígbà tó dà bíi pé kò sí ìrètí kankan mọ́, Ọlọ́run ránṣẹ́ sí Pọ́ọ̀lù pé ìrètí ṣì wà.

ÌTÀN 113

Pọ́ọ̀lù Ní Róòmù

Báwo ni àpọ́sítélì ṣe máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ g̣ẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n lọ́wọ́?