ÌTÀN 111
Ọmọkùnrin Kan Tó Sùn Lọ
YÉÈ! YÉÈ! Kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbí? Ṣé ọmọkùnrin tó nà gbalaja sílẹ̀ yìí fara pa ni? Wò ó! Pọ́ọ̀lù ni ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó ń jáde nínú ilé yẹn! Ṣó o rí Tímótì pẹ̀lú níbẹ̀? Ṣé ọmọkùnrin náà já bọ́ láti ojú fèrèsé ni?
Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Pọ́ọ̀lù ń sọ àsọyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Tíróásì. Ó mọ̀ pé ó máa pẹ́ gan-an kóun tó tún fojú kàn wọ́n torí pé òun gbọ́dọ̀ wọkọ̀ ojú omi lọ lọ́jọ́ kejì. Nítorí náà, ó fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di ọ̀gànjọ́ òru.
Ó ṣẹlẹ̀ pé ọmọkùnrin tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì yìí jókòó lójú fèrèsé, àmọ́ oorun gbé e lọ. Àfi bó ṣe tàkìtì látojú fèrèsé, tó wà ní àjà kẹta, tó sì ré lulẹ̀! Ohun tó fà á tí ìdààmú fi hàn lójú àwọn èèyàn tó ò ń wò yìí nìyẹn. Nígbà tí wọ́n sì fi máa gbé ọmọkùnrin náà, ohun tí wọ́n ń tìtorí ẹ̀ jáyà gan-an ti ṣẹlẹ̀. Ó ti kú!
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ọmọkùnrin náà ti kú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí ó sì gbá a mọ́ra. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má ṣe dààmú, ó ti jí!’ Ó sì ti jí lóòótọ́! Iṣẹ́ ìyanu ni! Pọ́ọ̀lù ti jí i dìde! Inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an.
Gbogbo wọn tún gòkè lọ láti lọ jẹun. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì. Ṣùgbọ́n wàá gbà pé Yútíkọ́sì ò tún jẹ́ padà sùn mọ́! Nígbà tó ṣe, Pọ́ọ̀lù, Tímótì àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò wọnú ọkọ̀. Ṣó o mọ ibi tí wọ́n ń lọ?
Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìrìn àjò ìwàásù rẹ̀ kẹta ni, ó wá ń padà relé. Nínú ìrìn àjò yìí, ọdún mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù lò ní ìlú Éfésù nìkan. Nítorí náà ìrìn àjò yìí gùn ju ti èkejì lọ.
Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Tíróásì, ọkọ̀ wọn dúró fún ìgbà díẹ̀ ní Mílétù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Éfésù ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà mọ́, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ sáwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ láti wá sí Mílétù kóun lè bá wọn sọ̀rọ̀ fún ìgbà ìkẹyìn. Lẹ́yìn náà, nígbà tó tó àkókò kí ọkọ̀ náà ṣí, ojú ro wọ́n láti rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń fi wọ́n sílẹ̀ lọ!
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkọ̀ yẹn padà gúnlẹ̀ sí Kesaréà. Níbi tí Pọ́ọ̀lù dé sí níbẹ̀, lọ́dọ̀ Fílípì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn àti ìdílé rẹ̀, wòlíì Ágábù kìlọ̀ fún Pọ́ọ̀lù. Ó sọ pé wọ́n á ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n bó bá dé Jerúsálẹ́mù. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Lẹ́yìn tó sì ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fún ọdún méjì ní Kesaréà, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Róòmù kí wọ́n lè gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Késárì alákòóso Róòmù. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí Róòmù.