ÌTÀN 115
Párádísè Tuntun Lórí Ilẹ̀ Ayé
WO ÀWỌN igi gíga, àwọn òdòdó ẹlẹ́wà àtàwọn òkè gíga wọ̀nyẹn. Ibí yìí lẹ́wà gan-an ni, àbí? Wo bí ẹtu ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ọmọ kékeré yẹn. Sì wo àwọn kìnnìún àtàwọn ẹṣin tí wọ́n dúró lọ́ọ̀ọ́kán lórí koríko tútù yọ́yọ́. Ǹjẹ́ kò ní wù ọ́ láti máa gbé nínú ilé kan tó wà nírú ibí yìí?
Ọlọ́run fẹ́ kó o wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè. Kò fẹ́ kó o ní èyíkéyìí nínú àwọn ìrora àti wàhálà táwọn èèyàn ń ní lónìí. Ìlérí tí Bíbélì ṣe nìyí fún àwọn táá máa gbé nínú Párádísè tuntun yẹn: ‘Ọlọ́run yòó wà pẹ̀lú wọn. Kò ní sí ikú mọ́ tàbí ẹkún tàbí ìrora. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ’
Jésù á rí sí i pé ìyípadà tó kàmàmà yìí ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tó máa ṣẹlẹ̀? Ẹ̀yìn ìgbà tó bá fọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní, tó mú gbogbo ìwà búburú àti àwọn èèyàn búburú kúrò ni. Rántí pé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé ó wo àwọn èèyàn sàn nínú onírúuru àrùn, ó tiẹ̀ tún jí àwọn èèyàn tó ti kú dìde. Jésù ṣe èyí láti fi ohun tó máa ṣe jákèjádò ayé hàn nígbà tó bá di Ọba Ìjọba Ọlọ́run.
Ṣáà ronú wò bó ti máa dùn tó téèyàn bá wà nínú Párádísè tuntun lórí ilẹ̀ ayé! Jésù pẹ̀lú àwọn kan tó yàn láá máa ṣàkóso ní ọ̀run. Àwọn alákòóso wọ̀nyí máa bójú tó gbogbo èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì rí i pé wọ́n láyọ̀. Jẹ́ ká wo ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti rí i dájú pé Ọlọ́run máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tuntun rẹ̀.