Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú
ÌWÉ ìtàn tòótọ́ ni ìwé yìí. Àwọn ìtàn tó wà nínú ìwé yìí wá láti inú Bíbélì tó jẹ́ ìwé tó ju gbogbo ìwé lọ láyé. Àwọn ìtàn inú rẹ̀ jẹ́ ìtàn ayé láti ìgbà tí Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀dá àwọn nǹkan títí fi di ìgbà tiwa yìí. Wọ́n tiẹ̀ tún sọ nípa ohun ti Ọlọ́run ṣèlérí láti ṣe lọ́jọ́ iwájú.
Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ̀ nípa ohun tí Bíbélì dá lé. Ó sọ nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn àti àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe. Ó tún ṣàlàyé ìrètí ológo ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn èèyàn.
Ìtàn mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116] ló wà nínú ìwé yìí. Apá mẹ́jọ la sì pín wọn sí. Ojú ewé kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan tó sọ nǹkan díẹ̀ nípa ohun tí a óò rí nínú apá náà. A to àwọn ìtàn náà tẹ̀ léra ní bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ ìtàn. Èyí á jẹ́ kó o lè mọ bí nǹkan ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn, èyí tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, èyí tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
Èdè tó lè yé àwọn ọmọdé la fi sọ àwọn ìtàn náà. Púpọ̀ nínú ẹ̀yin ọmọdé lẹ ó lè kà á fúnra yín. Ẹ̀yin òbí á rí i pé inú àwọn ọmọ yín kéékèèké á dùn pé kẹ́ ẹ máa ka àwọn ìtàn wọ̀nyí fún àwọn léraléra. Ẹ óò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí tọmọdé-tàgbà nífẹ̀ẹ́ sí wà nínú ìwé yìí.
A tọ́ka sí Bíbélì ní òpin ìtàn kọ̀ọ̀kan. A gbà ọ́ níyànjú pé kó o ka àwọn ibi tá a ti mú ìtàn náà nínú Bíbélì. Tó o bá ti ka ìtàn kan tán, kó o tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tá a béèrè lórí ìtàn yẹn. Wàá rí èyí lẹ́yìn Ìtàn 116, kó o sì gbìyànjú láti rántí ohun tó jẹ́ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.